Ominira da?




6

Ominira da?


Ni iwoye temi, asiko idajo ranpe sele si die ninu awon oloselu ile naijiria lose to koja, awon agba si bo, wonni: oye to kan ara iwo, on bo wa kan ara ede. Opo nkan lo si jeyo ninu esi ibo ose to koja yii.
Mo so pe die lara awon oloselu, opo lero pe nitori Aare wa lara awon ti o jakule, anilati so pe opo awon oloselu, sugbon ko ri bee nitori aare naa je okan lara awon oloselu ni, bi o tile jepe o je okan gboogi laara won.


Asiko idajo yii ko dede sele, opo sini nkan to fa ijakule opo ninu awon ti o fidi remi yii. Iwa ajebanu to gaaya ni akoko ninu oun to le won danu, ijo-ra-eni-loju naa si tun pelu ara iwa to yo won kuro nijoba bii jiga! Agbara kan ti bale awon oloselu waa lati nkan bii odun meridinlogun seyin ti o si ntan won je lati maa ronu bii pe ikawo won ni awon ara ilu wa lai mo pe awon ara ilu gan maa reke ija sile ni.
Ijoba Aree ‘ana’ yii ko tile bikita nipa nkan ti awon ara ilu nso bikose eyi ti awon alaba-sise po re ba fii tan je, gbogbo eniti ko ba ti gbee lese ni ota re, ijoba yii kii fee gbo ki enikan se atako nkan ti o ba se, kaka ki o fi oju sunukun wo nkan naa seni eniti  onsoro yio di ota re, paapa julo yio sope egbe alatako ni eni naa ti wa, gbogbo awon ti won nti Aare ‘ana’ yi ti ki enu won bo’go niisinyii, ko pe osu meji mo ti ijoba naa yio lo lori aleefa.


Awon ara ilu nilo lati la oju won sile gidi gan nitoripe opo ninu awon ti o wa nile-asofin-agba je awon ti won kuro ninu egbe ti koboko iya mu ninu eto ididbo ti ase tan, won kii se eyan tuntun kan tabi won eniti egbe alatako diidi fasile, pupo ninu won yapa lati darapo mo APC ni, o to senato bii ogbon kaakiri ile naijiria to dara po mo egbe APC lati PDP, boya laipe yii ni tabi bi odun die seyin,fun apeere ranpe: Dr Bukola Saraki, Rabiu Kwankwaso, Dino Melaye, Lafiagi, ati beebe lo


Ti aba wo iru nkan bayi o fi han pe egbe lo yi pada kii se awon eniyan inu re, Aare ko sile da se ise yii bikose lati gbarale awon asofin ti o je omo egbe re ki ise naa le yori kia, sugbon niwon igba to je eto ara awon oloselu yii ni won dun wa sinu egbe tuntun yi kii se ona ti gba mekunu sile ninu iya. Dandan ni fun awon ara ilu lati ma dake ninu wiwa ona abayo si ominira to yanranti ti yio si lalope!

Ka tun fi re pade! 

Comments

Popular posts from this blog

Eto ilera wa gan an mehe

Ijoba awaarawa yii dun bi?

Ijoba tuntun se kia…