Iru iyipada wo? 2




5
Iru iyipada wo? 2
Ni iwoye temi, oloselu ati ara-ilu ile yi ko yato si ara won. Alawada gbaa ni awon oloselu ile yi, bee si ni aderin-po-soonu ni awa ara ilu naa. Opolopo igba ti awon aisedeede ba nwa ninu isejoba ni awon ara ilu fun ra won ma nba oloselu salaye idi ti aisedeede se wa. Kaka ki awon ara ati omo apapo orileede yi dide lati bu enu ate lu iwa ajebanu,se ni won a di agbejoro fun awon oloselu ti enu a si ya awon perete ti won tako ijebanu ijoba. 

Ijoba apanilerin julo ni ijoba apapo ti o nselu lowo bayi, awon ti ipinle naa ngbiyanju ninu ere ori itage o sugbon, Aare oni je okan gboogi ninu awon alawada. Fun apeere: Aare ti se igbakeji gomina tele, lai-rokan-si o di gomina, lojiji odi igbakeji Aare apapo orileede Naijiriya, lai-fokan-si otun di Aare, sugbon pelu gbogbo asiko iyipada okunrin talaka yii, ‘bata’ ti ko wo ri ni o fi nse opolopo ipolongo ibo ti o gbee wole ni akoko. Awon omo ati ara ile yi ko tile beere ibeere to yanranti lowo ‘alaiwobatari’ yi nipa kilofe se lati yi ilu yi pada si rere. 

Nse ni gbogbo won so pe ki won je ki o se ijoba nitoripe ekun eya Ijaw ko tiise ijoba ri ati pe okunrin naa ko wo bata fun igba pipe! Oro bata wiwo yi ni o gbode kan titi ti eto idibo odun 2011 filo, Aare wole tan o wa bere iwa orisirisi ti ko jo ti eni tio ti gbaradi lati je asaaju ri. Iwa ajebanu ti gbode ju ti tele lo, epo petrol di nkan to wan ju bo se ye lo, Owo nsonu lapo ijoba lailalaye, Ina oba ti gbowoleri ju bo se dun mo, ina gan tun ti baje ju bo seye lo. Awon a-femi-sofo Bokoharam gbile gan,koda won gbowo ori ni odindi ilu bii meedogbon! Sibe seni awon amukunmeko omo orile ede yii npariwo iyipada! 

Bo tile je pe awon egbe alatako to lagbara julo nile yi naa ko ja mo nkan-kan, iwa ole jegudu-jera, anikanjopan ko jina si awon naa. Ipanilerin tie lo je lati rii pe awon ti won wa ninu egbe ti Aare olukuna lati se rere fun ilu tunti darapo mo egbe alatako, ofihan gbangba pe kii se ona ati tun ilu to lo wa lookan aya won biko se bi won yio se pin ola ati ola orile ede yi mo ara won lowo. 

Gomina egbe alatako lo so fun ara ilu ni 2012 pe bi ijoba apapo ko bayo sobsidi kuro ninu owo epo ilu yio tuka, Edo ni okunrin naa ti wa. Se iru awon ti oye lati ma ba pari wo iyipada ni eleyi? Mo gbiyanju lati tun apede awon egbe mejeeji si ede abinibi tiwa lona to rorun mo wa ripe, Change je iyipada,looto otun tumo si ‘paaro’! bee na ni Transformation naa tumo si Iyipada!   

Owo awa ara ilu lowa lati mu ojo ola wa ni okunkundun fun isejoba to lagbara ire ati itesiwaju alalaafia. Ka dide lati maa ja fun igbe aye irorun to lapeere ju ki a je ogbufo fun oloselu lo!

Katun fire pade!   

Comments

Popular posts from this blog

Eto ilera wa gan an mehe

Ijoba awaarawa yii dun bi?

Ijoba tuntun se kia…