Ile ileri jina



9
Ile ileri jina

Ni iwoye temi, ise pupo ni gbogbo omo apapo orile-ede Naijiria ni lati se, papa julo lori ‘ijoba tuntun’ ti o sese de yii. Aku ojo meta kan, a si kuu roti-roti ijoba apapo wa yii. Kayeefi nla lo nje fun mi pe awa ni ilu to ni opolopo ohun alumoni, eyii to wa ni opo ipinle tie ni ako ti fowokan rara. Awon alumoni yii po debi pe o tile nda awon olori ile yii laamu, won ko mo biwon se fe loo tabi ona ti won yio gba loo. Sugbon ti epo robi yii lo si fee lagbara julo lenu looloo yi. Ani epo to le bo bii apapo orile ede mefa lai tie lo nkan miran,fun apeere ile Japan ko tile ni ida kan lona ogorun ninu nkan ti ile Naijiria ni sugbon ilu naa ti di apeere awokose to laami-laka fun ile Naijiria.

Pelu bii epo robi yii se wa po to, opolopo iya ni ilu yii nje. Gbogbo nkan to le ni ogun to dabi eeni lara epo robi ni a nfi owo goboi ra, afefe idana to ye ka tun maa rilo lofe-lofo tun nsofo danu.Kekere wa ni gbogbo eyi ti ame-nu bayii, seni owon gogo epo ti wa fe di baraku nile yii, ijoba Jonathan ko tile kaa si oun to se Pataki lati je ki awon to wa nidi oro Naijiria ri oro je.Mo se bi won ni akii leni nimusan ka mu kikan, oro ijoba Jonathan koja bee, seni o ma nfi epo da ara ilu lagaara. Ni nkan bii odun meta seyin sa dede ni a ji ni ojo kini osu kini odun tuntun (2012) ti a si gbo pe se ni wo yio fi owo kun owo epo, opo omo ile yii lo yari kanle, lati Eko titi de oke Oya, ile Yibo gan o gbeyin, orin aa nigba ni gbogbo koowa nko, Ija yii gbawa die lowo N140 ijoba si bii N95, bi o tile je pe N65 ni a nra tele, a fi ara mo iwonba change ti o yo lori ele yii.

Lati igba naa ni ile yii ti pada si ese aaro, ki omo alaso wa maa wo akisa ni,omo eleran wa nje eegun, awa la ni epo sugbon dandan ni fun ijoba yii lati fiya epo j’ewa! Ijoba to na bii tirilionu meta fun eto idibo nje awon onisowo tio ngbe epo wolu ni owo to le ni ogorun meji bilionu! Bee ka fi owo wonu ni ka muu mora,ka ma soro ni awon alaimokan nwi. Nje o ye ki omo oba maa se bi eru? Ki omo elesin maa rin se? Ijoba tio nbo naa ko ii tii se alaye lekun-rere bi yio se koju awon isoro yii. Isoro ina mana-mana, owon-gogo epo ati aisi re, ona ti yio ja geere ti yio si lalope. Eyi fi han pe ona ile ileri wa si jina ju bi a ti ro lo. Gege bi omo ati ara ile yii, ani lati ma kaare, ki a si maa jigiri si ipinu ati d’ele ileri! Bi oti le wu ki o  jina to, kaa ri daju pe dandan ni fun wa lati de be. Ko tii ya fun wa lati sinmi ati ma beere eto aye daade wa!

Ka tun fire pade! 

Comments

Popular posts from this blog

Eto ilera wa gan an mehe

Ijoba awaarawa yii dun bi?

Ijoba tuntun se kia…