Mista Gomina
22 Mista Gomina Ni iwoye temi, ipinle Eko ni o fee je ilu to duro deede julo ni Naijiria. Lati odun merindinlogun o le ni eeya egbe kan naa ti n dari eto ijoba ipinle yii. Ojo idibo lee le gan-an, o si le fee di ogun, sugbon egbe kan naa yii ni o n jawe olubori. Gbogbo atotonu yii wa ja sipe ko ye ki ilosiwaju ma maa tesiwaju, paapa julo ninu eto ise joba ipinle Eko. Ijoba to wa ni ipinle Eko ma n se aya-gban-gba pe awon je egbe ti n da si oro mekunu, ti a mo si ‘welfarist party’ . Ko da won ma n so pe egbe ti o n wa ilosiwaju fun omo-niyan ni egbe won. Sugbon gomina ti o soju egbe naa koja lo owo agbara to po gan paapa ti o fe jo ti oloogun. Ise itesiwaju ko fi gbogbo ara le to bi a se muu ninu ijoba to sese koja l’Eko yii, bee si ni ko ye ko tun fi gbogbo ara wo le to bi oga agba tuntun see n mu lo yii. Ki a ma baa si ara wa gbo, gbogbo ilu ni yoo ni ofin to dee. Ti won ba n sese n tun ilu se tabi ti won ba ngbiyanju lati so ilu di tuntun, orisirisi ifarada n...