Posts

Showing posts from October, 2015

26 Mo ti so fun wa tele!

26 Mo ti so fun wa tele! Ni ose to ko joka ni a soro nipa aibikita awon ijoba wa lori oko-ajagbe-ejo. Ai tii ko ifa nle, seni ifa oro naa se de gongo ni ose yii. Ona bii marun-un   ni isele ijamba oko-ajagbe-ejo ti sele ni ose ti a wa yii ni ilu eko nikan, Warri ati Oweri naa fara kaasa ninu ose ti ise laabi yii se lodi si awon omo orileede yii. O nira die lati so pe okan   buru ju ekeji lo nitori ko fee si eyi ti ko la emi lo. Eyi ti o sele lati de ACME ni ona Ogba-Ikeja nikan ni o ni o da bi kereemi. Gbajugbaja ninu isele laabi yi ni ti Ojuelegba ti agolo eyin oko yii ti rebo lati ori afara, ti o si lo oko to ja le lori tutu. Ti a ba wa nso nipa aisedeede ijoba, awon eeyan kan ro pe se ni a ko moomo maa n bu enu ate lu ijoba yii. Awon iwa palapala ti awon ti won wa ni ijoba wa nwu ni o fi aye iwaibaje sile lawujo wa. Enu lasan ni awon ijoba wa ma fi n se idekun iwa odaran, eyi si je oun nla ti n se akoba fun wa gege bi orileede, sugbon nigba ti oro naa ko ba i...

25 Mista Gomina leekan si

25 Mista Gomina leekan si Adupe pupo lowo gbogbo awon ti won npe wa ni ti gidi lati fi erongba won han lori awon ohun ti a n ko ninu iwe Iroyin-Owuro, paapa julo ninu abala Gbangba Dekun . Eyi fihan pe ko see se lati je adagun nigbati eeyan ba nko nnkan sinu iwe-iroyin. Ope pataki lowo yin oo! Gege bii ise mi lati maa yannana isejoba ati iwa i-bara-eni-gbe pelu eto oselu, ni eyi to jinle ninu eto oselu awaarawa ti a n se lowo yi, mi o ni se alaise bee ni ose yii.   Ni ose meji seyin, mo pe akiyesi wa si awon aisedeede awon oko-ajagbe-ejo, gbogbo oju si ni o ri abajade gbogbo ariwo ti mo n pa ni ose to tele. Ilu Eko tii n jo oun to dorikodo bayi. Awon awako tie ti gbe iwakiwa wo, isowo wa moto ni ilu Eko ti yato bayi, eni to ku ni a ni ko kuu re, sugbon Gomina tuntun tun ti ru oku koja ile! Ewo ni gbogbo ki ilu di alailofin bii eyi ti a n gbe lowo bayi? Ilaji ina ti n pe oko ranse ( traffic light ) ni ko sise mo. Ina kan tie ma n tan lori birij Carta , ti eeyan ba n...

24 Se ina monamona naa ti de ile yin?

24 Se ina monamona naa ti de ile yin? Lara awon ti won nko iwe ranse si mi beere ibeere lowo mi pe boya mi o ri nnkan-kan ti o daa ninu ijoba ti a n se lowo yii. Onkowe naa ni bi mi o ti e ri nnkankan   o ye ki n ri ina oba to ti wa kaakiri. Looto ni, o jo pe ina oba ti duro ‘deede’ de ibi kan ni awon agbegbe kan, sugbon opolopo awon agbegbe ni koo tii ni opo ina debi pe won yoo ni ina. iwoye ti mo ni nipa ilu wa nigba-miran nipe, ki oloye Obafemi Awolowo yoju lati oke ki o si ri ibi ti awon eya to ni erongba nla fun ba ise de.  Bawo ni baba Awolowo se maa wo awon ‘omo’ ti o fi sile, bawo ni awon omo naa se ndari ilu ti Awolowo ja fun ki o to lo? ni 1959 ni Awolowo ti mu telifisan wa si ile yoruba, 2015 opolopo yoruba koo ti ri ina wo telifisan naa. Awon ona ti baba ti da konta sii lati aye ojo yen si ni opolopo awon ona ti o wa ni igberiko wa do ni. Bawo ni Awolowo yoo se maa wo igbe aye awon omo yoruba ni morere ti o wa bayi ti o tin je pelu awon awo i...

23 ARASE

23 ARASE Ope mi po lowo awon ololufe Gbangba Dekun ninu iwe Iroyin-Owuro, bi e se n pe wa pelu awon adura repete ti e n fi ranse si wa jo wa lo ju pupo, e seun ile yin naa ko nii daru,ona yin yoo si dara. Lara awon eka tii mu ki ijoba awaarawa se e gbadun ni olopa wa. Sugbon olopaa ile Naijiria yii ti gbe ewu iwa ibaje tii koo see gba danu wo. Ojoojumo ni awon olopaa wa n fi kun awon iwa buruku won. Ti won ba jaja se ise ti a gba won fun, se ni gbogbo ara ilu yoo maa pariwo pe mesaya ni won. Se owo eyin ni ka so ni? Tabi iwa ta lo fe mu mi ti won wu? Ati opolopo iwa ti ko see fenuso ti won n wu. Apeere kan ni iriri ti emi funra mi ma n ni pelu awon olopa ti won wa ni agbegbe Berger/Isheri,awon olopaa   to wa nbe ko jo olopaa rara. Oga won so fun awako ko boole ninu moto,o si bere si ni maa ba iyawo oniyawo soro ife! Olopaa to ye ko maa boju to ara ilu, o tun raaye ati maa ko enu ife si iyawo oniyawo leenu ise! Laibikita fun oun ti o le teyin re yo, nitori o mo ...