23 ARASE



23

ARASE

Ope mi po lowo awon ololufe Gbangba Dekun ninu iwe Iroyin-Owuro, bi e se n pe wa pelu awon adura repete ti e n fi ranse si wa jo wa lo ju pupo, e seun ile yin naa ko nii daru,ona yin yoo si dara.
Lara awon eka tii mu ki ijoba awaarawa se e gbadun ni olopa wa. Sugbon olopaa ile Naijiria yii ti gbe ewu iwa ibaje tii koo see gba danu wo.
Ojoojumo ni awon olopaa wa n fi kun awon iwa buruku won. Ti won ba jaja se ise ti a gba won fun, se ni gbogbo ara ilu yoo maa pariwo pe mesaya ni won. Se owo eyin ni ka so ni? Tabi iwa ta lo fe mu mi ti won wu? Ati opolopo iwa ti ko see fenuso ti won n wu.

Apeere kan ni iriri ti emi funra mi ma n ni pelu awon olopa ti won wa ni agbegbe Berger/Isheri,awon olopaa  to wa nbe ko jo olopaa rara. Oga won so fun awako ko boole ninu moto,o si bere si ni maa ba iyawo oniyawo soro ife! Olopaa to ye ko maa boju to ara ilu, o tun raaye ati maa ko enu ife si iyawo oniyawo leenu ise! Laibikita fun oun ti o le teyin re yo, nitori o mo pe ko si nnkan to le teyin re yo.

Awon  Olopaa wa ko ni ikora-eni-ni-ijanu kankan bo ti le wu ko kere to. Mo tile tun gbo pe oko-iyawo ni laye,oun o tun gba ona yen mo. Oun miran tun sele loju mi gan-an, olopaa kan naa yii lo tun kii iyawo elomiran mole to tun fe fee lenu ise? Mo wa woye pe se Arase gbe awon Olopaa yii sibi lati maa ko enu ife si awon iyawo ni? Owe awon agba kan si so pe afenilaya ko fojure wo ni. Bawo le se fe mo boya to ba di ojo kan, awon olopaa yii ko ni wa esun nla kan si orun awon ti won pe aya won yii.

Oye ki a tun awon olopaa wa ko ni iwa omoluabi ti o ye ki won maa wu loju popo.
Mo fi oju ara mii ri olopaa to lo mu oti ninu moto eni to mu, enu ya mi gidi nitori oti to le gan-an ni olopaa yii gba lowo onimoto yii to si muu ninu re. Bawo ni iwakiwa kose niba le olopaa to ti mu oti yo laaaro kutukutu. Aa ri awon olopaa ti enu won yoo maa bu tii laaaro kutu fun oti. Ko si eni to ni ki enikan ma gbadun aye re sugbon kii se lenu ise ti o n gba owo osu fun.

Awa ara ilu gan-an nilo lati maa pariwo awon iwakiwa ti awon ti a gbe ise fun ba n wu. Kii se ki a kan maa wo won loju lasan. Ibanuje lo je pe olopaa ti a n fi owo ilu san owo osu fun gan-an ni o maa n deru ba ara ilu to n san owo fun-un nipa awon iwa ti ko  see gbara le ti won n wu lawujo.
Ka tun fire pade! 


Comments

Popular posts from this blog

Eto ilera wa gan an mehe

Ijoba awaarawa yii dun bi?

Ijoba tuntun se kia…