26 Mo ti so fun wa tele!
26
Mo ti so fun wa tele!
Ni ose to ko
joka ni a soro nipa aibikita awon ijoba wa lori oko-ajagbe-ejo. Ai tii ko ifa
nle, seni ifa oro naa se de gongo ni ose yii. Ona bii marun-un ni isele ijamba oko-ajagbe-ejo ti sele ni ose
ti a wa yii ni ilu eko nikan, Warri ati Oweri naa fara kaasa ninu ose ti ise
laabi yii se lodi si awon omo orileede yii. O nira die lati so pe okan buru ju ekeji lo nitori ko fee si eyi ti ko
la emi lo. Eyi ti o sele lati de ACME ni ona Ogba-Ikeja nikan ni o ni o da bi
kereemi.
Gbajugbaja
ninu isele laabi yi ni ti Ojuelegba ti agolo eyin oko yii ti rebo lati ori
afara, ti o si lo oko to ja le lori tutu. Ti a ba wa nso nipa aisedeede ijoba,
awon eeyan kan ro pe se ni a ko moomo maa n bu enu ate lu ijoba yii. Awon iwa
palapala ti awon ti won wa ni ijoba wa nwu ni o fi aye iwaibaje sile lawujo wa.
Enu lasan ni
awon ijoba wa ma fi n se idekun iwa odaran, eyi si je oun nla ti n se akoba fun
wa gege bi orileede, sugbon nigba ti oro naa ko ba i tii farahan awon eeyan ma
n ro pe ko si idi fun wa lati maa so.
Igbe aye to
dun, to layo, to si larinrin laisi ifoya dun pupo lati maa gbe. Oun si lo ye
gbogbo awa olugbe Afrika, awa omo Naijiria, paapa julo awa adulawo ti a je
Yoruba nitoripe alumoni wa fun wa, ti o to lati ba gbogbo aini waa pade, sugbon
awon a je loju onile ti a gbe aye wa le lowo ni won je ko polukurumusu!
Ninu
ihalahilo ni opo awon ebi maa wa lori ose ti oko-ajagbe-ejo se ni ose to koja
yii, ipayinkeke si ni gbogbo isele naa yoo je fun awon ebi ti oro naa kan. Ise
ijoba ni lati mu itosona to to ba eto irina ati awon ohun elo irina ti oko je okan lara won.
Kilode ti
awon oko yii fi n rin ni osan gangan? Ki lode to je pe awon oko ti aye won ti
baje yii, ti emu won ko le mu irin mo lagbede si ni a n lo lati maa fi gbe awon
kontena waa? Kilode to je pe nigba ti opolopo ilu ti se awon oko oju irin to n
fee sare ju moto lo awa sii n fi oko-ajagbe-ejo oniro ko awon eruu wa? Ki lode
to je pe awon oko godoro yii ma n gba ori afara? Ki lo de to je pe opolopo won
ko nii ijanu to peye ? kilode to je pe eru to wa leyin kontena le jabo nigba to
ba wuu ti ko si ni si ofin kole-kole kankan loju ese?
O di ojo ti
kontena ba ja lu omo gomina kan tabi alee oloselu kan ki won to moo loran. Lo
se to koja ni mo n so pe awon iwa abikita waa lori awon nnkan to jo keekeke le
se opolopo jamba,ti mo si soro lori awon kontena yii, lara re ni awon to sele
lose yii ti kontena pa oke-aimoye eeyan sorun apapandodo. Ise gbogbo ara ilu ni
lati boju to igbesi aye wa funra wa, ki a si ke gbanjare lodi si gbogbo oun to
ba je kudiekudie ijoba. A kii se agbenuso fun oloselu, igbe aye wa lo wa lowo
won, a ni lati se alaye bii won se ma je ko gun!
Ka tun fire
pade!
Comments
Post a Comment