Se o ti ya?
7
Se o ti ya?
Ni iwoye
temi, iwa ajebanu ti di baraku nile Naijiria, osi je oun ti o nilo abojuto gidi ju bi a se
ntanra-wa-je-to lo. A ku ojo meta, asi ku rotiroti eto idibo to koja lo yii, mo
lero pe a jo ngbadun ara wa ninu abala ‘Gbangba dekun’ yii? Laipe maa bere sini
maa fesi si awon iwe ti e fi nsowo si wa.
Opolopo omo
ile naijiria ni o ti gbeke won le Jenera Muhamodu Buhari lojuna ati gba won
lowo ogunlogo isoro to bale won ati ti ongun ile yi l’esin, sugbon aafe di bi
iyanu pe awon ati ogagun-feyinti yio ja
nigbehin gbehin ni. Kilode ti iwoye toni fi gba ojuna yii? Idi nipe, ile yii ti
baje ju bo se ye lo, awon nkan ti dorikodo koja bo se ye, ona ti loju po ju bo
se ma nsele lo, oko eru yii sii tii fee mo awon eyan ile yi lara ju bi won se
ro lo. Kii sepe ogagun-feyinti yii gan papa julo je olugbala, sugbon o jo pe o
nife lati mu awon oun kan to nile yi.
Iwa ajebanu ile yii gagaara koja keremi, seti
awon olopa alabetele la fe so ni? Awon ti o ye ko je agbofinro nile yii ti di
arufin! Gbogbo ona si ni won gba lati fiba oruko ilu yi je, won a gba abetele
lowo ole,jaguda, onimoto,olokada,ountaja ati gbogbo enikeni ti o ba sesi gba
iwaju won, o le koko lati fi ejo olopa ile yi sun. Iwa abetele ti wa di baraku
lara opo omo ile yii. Koda o ti koja agodo awon olopa, awon ara ilu funra won
gan tii ri abetele gegebi oun to ‘Noma’. Ti o file je pe ti eyan meji
ba nse nkan to je mo owo, won a diidi siro abetele mo owo oun ti won ban se.
Olopa ile yii ti wa baje koja bo se ye.
Eyi si je okan kanka ninu oun to le fo
ilu yi mo ti a barii yanju. Ibaje ile yi ti kamama rekoja oun ti won yio ka
kuro laipe lo,ti a ko ba si ti ri won ka kuro ise ilosiwaju ilu yii yio fale
koja bi a se ro. A ko menu ranpe ba awon agbofinro ni nitoripe awon gan wa lara
irinse nla to le mu aseyori wa , looto iwa ajebanu,aibikita ti wo wa lewu
sugbon ti ogagun ba mu ti awon olopa yi gbo kia yio se iranwo onikia fun
idagbasoke.
Ise awa ara ilu ni lati
masun kia a si maje ki ijoba wa sun titi ti a o fi maa gbe igbe aye irorun.
Aye ko fibe gbawa pupo loni, sugbon a o tesiwaju lori oro yii laipe.
Katun f’ire
pade!
Comments
Post a Comment