Ijoba tuntun se kia…
17
Ijoba tuntun se kia…
Ope pupo lowo
gbogbo awon ti won kowe ranse ati awon ti won pe wa lati fi eero-ngba wo han
lori apileko Gbangba Dekun yii.
Bi o tile je
pe mi o fe fii bee ko nipa ijoba ‘tuntun’ ti a nlo lowo yii lasiko yii, nitori
oro po ti a ni lati dasi. Sugbon ti a ba ni ki a dake wo bi won se n tuko
orileede yii, wahala nla ni gbogbo wa nwa. O ti le ni osu kan gbako ti a ti bo
sinu ijoba change yii, sugbon orin to
jo tatehinwa naa la si ngbo.
Ki Aare
Buhari to gori alefa ni opo omo orileede yii ti fee mo bi ijoba seri. Ijoba to
koja ti fi iwa jegudujera ati ajebanu-alaibikita na gbogbo owo orileeede yii
je, koda kii ilu ma baa baje ju bayi lo ni opo omo ilu yi se fi ibo le oga Jona
lo. Sugbon kii se pe ki Aare ‘tuntun’ baa lee fun wa ni awijare ni won se dibo
yan.
Awon nkan ti ijoba tuntun yii seleri ko fi
gbogbo ara le lati se to bi o se njo bayi.
Awon isele
bii mefa kan se oju mi lose to lo yii ni mo se woye pe boya ni ilu yii le ni
ilosiwaju to je erongba awa kan nile yi. Ma fi enu ba die ninu awon isele yii.
Sa dede ni mo ri okunrin Lastma kan
ti awon omoota kan ntele ni agbegbe Allen round-about to lo si Aromire ni
Ikeja, ti won si npariwo “bobo naa da?”.
Kete ti won
ri ‘bobo’ naa ni won bere si ni maa da igbaju boo. Enu ya mi pupo nitori mo ro
pe agbofinro-igbokegbodo oko ni oye ki Lastma
je kii se agbero. Mo rora tese duro die, mo beere pe kini odomokunrin yii se,
wo ni o ya lastma to gbowo kobe lowo oloko, won ni se o n sise fun ijoba ni abi
kini o kan ‘bobo’ yii to fi wa n ya foto eni-eleni to n sise tie.
Aya mi ja
tori emi naa ti wa ni iru ipo yii ri ni Maryland bus-stop ni gba die seyin. Mo
ba omokunri yi bebe die ni won se fi sile, olopa paapa da si oro yii pe “ki lo
kan bobo yii now?”.
Ikan tun
nipe ni nnkan bii aago mokanla koja ni ojo Thursday
ti a lo tan yii ni mo n gbe oko bo lori Third-mainland
bridge, mo ko ri awon meta kan ti won gbiyanju lati gbe odomokunri kan ju
sinu odo nla ti o wa ni ori bridge yii sugbon ni akoko yen ko si nkan ti mo le
ju ki npe olopa lo, kete ti mo de opin bridge
yii ni mo so fun awon olopa ti won wa ni Adekunle Police Station, koda gan inu oko ayara-bi-asa won ni won
wa, olopa yii ni ki n yi oko pada gba one
way ka maa lo sibe.
Mo ni sebi
mo ti so ibe fun yin ati pe eyin ni ibon, olopa kan ninuwon ni, “eehen se awa
lo ye ki a wa lo ku? Mista Man geraotu!”.
Kia ni mo ferege, sugbon ominu nkan mi, nko si le sun moju. Opo nkan ni
o n sele ti o je pe bi ijoba ile yii se ri ni o je ko maa ri bee.
Ijoba tuntun
yii seleri aabo to peye sugbon, bii ijoba yii se nlo afaimo ko ma je pe bi a se
wa naa ni ase maa ma wa lo tabi ki awon nkan buruku miran tun bere sini maa je
yo.
Buhari ti
gbogbo awon eniyan ni ko ni gba gbere ko tie bere pelu iru owo bee. O yan awon
eeyan meji si ipo kan naa, eyi si tun deru ba mi pe sebi awon pipu yii seleri
pe awon yoo din owo ti ijoba nna ku ni,ewo ni ka tun yan special adviser ati senior
special adviser sidii ise kan naa. Gbogbo ipinle ni yoo fi o kere tan
minista kookan ranse si ijoba apapo, bawo wa ni ase maa din owo ti ijoba nnna
ku?
Opolopo awon
ipinle si ni ko ri owo osu san, bawo wa ni idekun yoo se ba ara ilu? Igbawo gan
ni awa ara ilu yoo bere si ni gbadun ijoba ‘tuntun’ won yii. Gbogbo wa ni a ni
lati mo pe awon oloselu ko yato sii ara won, ko si to fun wa la ti maa je
agbenuso fun awon oloselu ti nsejoba, yala kii a maa ba won faa ki igbe aye irorun
le ba wa. A o te si waju lose ton bo.
Ka tun fire
pade!
Comments
Post a Comment