400 milionu
19
400 milionu
Akuu aseku odun, a sii ku gbogbo
igba. Lara awon ti won nfi iwe sowo simi lo ri ero alatagba ti a n pe ni internet beere lowo mi boya ijoba le te
ara ilu lorun, awon kan ni awa ara ilu ko diidi ya alaimoore ni.
Pe paapa julo ijoba to wa ni ita
bayi ti gbe awon igbese lati mu aye derun fun awon ara ilu, awon apakan yii si
fe ki awa naa fi oju ibe riran.
Maa bere apileko toni lati beere pe
kini ojuse ijoba? Awon ijoba wa ti fi iya je wa to bee ti a ko fi mo pe se ni o
ye ki a maa gbe bi oba.
Esuru ile ti yii ti padi da, seni o
n le ada. Awon to ye ki o maa bo wa ti di eni ti a n bo.
Ijoba ni o ni ojuse to le, to pon
dandan lori ara ilu, paapa julo lati maa toju ara ilu. Nitoripe gbogbo omo ilu
ni o jumo ni alumoni ti won fii nse ijoba, kii se pe eni ti won yan sipo ni
lati je gaba lee lori. Olusin-ara-ilu ni o ye ki awon ti won wa ni ijoba je,
kii se pe ki awon ara ilu maa sin won, tabi ki won maa bu ola kan to yato fun
won. Ojuse kan pere ni ara ilu ni kii si se si ijoba si ilu ni!
Ojuse ti ara ilu ni lati bowo fun
ofin to n dari ilu! Enikeni to ba wa ni ijoba le kuro nibe lola, Sugbon ofin ni
nnkan to pa gbogbo ara ilu po. Fun idi eyi ko si idi fun wa lati ma ri
kudie-kudie ijoba. Gbogbo ohun ti won ba nse ni o ye ki a maa wo finni-finni.
Fun apeere ijoba Buhari ko fe gba
moto tii-ro-ota-danu ti owo re leni 400milionu, gbogbo awon isangbe re si ja
sita won bere sii ni pariwo ‘hosana, mesaya de!’, Eleyi ko tumo si nnkan nitori
ti a ba je ilu ti o ni ori pipe ni, ni asiko ti awon ipinle bii ogun ko ri owo
osu gba nje o ye ki ijoba wa tun maa na inakuna kankan? Se bi oko kan ni aare
to lo tele ri nlo? Kilode ti asese tun fe lo ra omiran fun aare to sese de? Se
oogun tii-nro-ota-danu lara oko ti tele ti ba je ni?
Awon isele po gan-an nile yii ti o
ma n fi han pe inu oko eru si ni a wa, ayaafi ti a ba setan lati ja ara wa gba
nikan ni a le mo riri ara wa. Ko si egbe kankan to fi gbogbo ara yato si ara
won ni ile yii.
Lara awon ipinle to je awon osise
lowo osu ni ipinle Osun wa, irin ajo mi lo si Osogbo si fi han pe awon ara ilu
kan ko tile mo idi ti ko se si owo lati san owo awon osise, sibe se ni won nse
rankadede fun gomina won. Ibeere temi nipe se gomina naa ko gba owo osu? Se
gomina ko gba owo mabimileere ti won pe ni sikioriti vote? Se awon komisona naa
ko gba owo osu? Se awon ti won jo nsejoba naa ko ri owo gba? Se idile gomina ko
ri ounje je? Sugbon mo pe opolopo idile ni osogbo ni ko ri owo jeun latari pe
won ko san owo osu fun won.
Ko si idi kankan fun wa lati maa
gbeja ijoba Kankan afi ki a ma so gbogbo ohun ti won ba nse, ki a si maa bu enu
ate lu ibi ti o ba ti ni ara ilu lara.
Ka tun fire pade!
Comments
Post a Comment