Ijoba tuntun se kia…2



            18
                          Ijoba tuntun se kia…2  
   
Igbesi aye awon eeyan to n gbe ni Naijiria ko fi bee jo awon oludari ilu yii loju. O je oun to ma n kan mi lomiinu pe awon ilu kan wa ti enikeni ko le fowo kan omo ilu won, koda ti awon ota iru fe ilu yii ba mu enikan lati iru ilu bee, nse ni inu won maa dun ti won a si maa fo fayo. Sugbon ko si nnkan to kan awon ti won tuko Naijiria pelu awon omo ile yii bikose bi awon se maa fi ijoba jogun oun to ba wu won.
E ku ojo meta. Se daada la pada ba ara wa ni ose yii? Afi ka dupe pe a si wa laaye pelu gbogbo laasigbo ti igboke-gbodo ona a ti je ati a ti muu ma n da sile fun wa ni orileede yii.

Ni ose to koja, a n woye awon nnkan-kan pelu ijoba tuntun yii, awon ohun ti won sele ri ti fee maa da bi eni pe ko ni see se.
Fun  apeere:  Ijoba tuntun seleri pe awon a maa fun awon ebi ti o ya talaka julo ni egberun marun losu(N5000) ti won ba gba lati gba abere ajesara fun awon omo won. Ijoba si ni yoo to milionu marundinlogbo(25000000) ebi ti yoo ni ipin ninu owo yii. Losu yoo to bi 125 bilionu ti owo naa ma je, owo tabua si ni yoo je lodun kan.
Akoko nipe bawo ni ijoba se fe mo awon ebi ti o ya talaka julo ni ilu ti ko ni akosile to yanranti? 

Naijiria ti ko mo iye awon ti won n wo inu ilu re loojo kan, se oun ni yoo mo iye awon ti won talaka julo? Ati pe bawo ni owo rogunrogun yii ko se ni bo si apa orileede yii ju ikan lo? Eto wo loti wa ni le ri lati dasi bi awon eeyan yoo se ma gbowo ti ko ni si pe enikan wa nibikan ti n nna owo awon eeyan je? Owo ifeyinti awon osise gan ko tii fi gbogbo ara ni iyanju to bee ju bee lo.

Ti awon ebi to fe gba owo yii ba je ida marundinlogorin (75%) lati oke oya bawo ni awon eya yooku ko se ni binu pe se ni ijoba n moo mo fi owo ara ilu bo awon eya kan? Ile Naijiria je ilu ti o ti pin yeleyele lori oro eya, ede ati esin.
Ijoba tuntun seleri pe awon yoo pese ise 720000 ni odun kan.
Looto ti ina oba ba moju duro, yoo rorun fun gbogbo eniyan lati ri nnkan-kan mu se. Sugbon ijoba Buhari gan an ni o di 2019 ki o to di pe ina ko ni seju mo ni gbogbo ile Naijiria. 

Diedie ni ojo nlo, oti le ni osu kan ti a ti ki ijoba yii kaa bo, kato wi kato fo, ogorun ojo a pe. Pelu bii ijoba yii se n lo to je pe ariwo ko si owo nle ni gbogbo wa ngbo kiri aa fee dabi eni pe ala ni awon ileri ti won se ki won to wole maa je lojuu wa.
Pataki ni fun wa gege bi ara ilu lati ma gbagbe pe ko fi bee si iyato laarin awon oloselu, ka si ma je ki won fi juujuu kan bo wa loju. Gbogbo igba ni ki a ma pe won si akiesi awon ileri ti won se ki won to gori aleefa. Ara ilu ni wa, awa ni mudunmudun ile yii to si, kii se ki a di agbenuso fun awon oloselu! A a tun maa tesiwaju lose to nbo.

Ka tunfire pade!    

Comments

Popular posts from this blog

Eto ilera wa gan an mehe

Ijoba awaarawa yii dun bi?

Ijoba tuntun se kia…