Ijoba awaarawa yii dun bi?
15
Ijoba awaarawa yii dun bi?
Fun ojo pipe
ni opo omo orile-ede Naijiria fi jiya lati gba ijoba awaarawa ti awon eeyan n
pe ni democracy. Koda lati aye oyinbo
amunisin ni awon ti won te Naijiria tuntun do gan ni a ti n ja fitafita lati
gba ijoba awa omo ilu ti yoo si ni ti awaarawa ninu.
Gbogbo laala
awon to ja fun ijoba awaarawa omo onilu lo ja si pabo nigbati oloogun gbajoba
ni odun 1963, lati igbayi ni okan awon eeyan ti wa loke ki won to le fi oju ri
ijoba alagbada.
Opo ojo lo
wa ti ro ti ile si ti fi mu ni Naijiria, sugbon ojo to n ro lowo yii ko fi
gbogbo ara yee awon eeyan. Ti a ko ba sora, ojo yi a pa teru tomo po, yoo si je
ki gbegiri waa san gege bii omo orile-ede.
Awon eeyan
ti bi mi pe kini anfani ijoba awaarawa? Ni idahun temi moni, ‘aaye ati le lanu
soro laisi iberu ni anfani kan soso to wa ni inu democracy ’.
Ijoba
awaarawa ko nii pese ina,omi,ona,eto aabo,ati beebeelo. Ijoba gangan nii peese
oun amaye-derun,ijoba tii sii se be ko ni oruko. Fun apeere gbogbo awon oun
amu-yangan nile yii, eyi to poju nibe ijoba oloogun lo pese won yato sii awon
eyi to ti wa nigbati Awolowo n se ijoba, gbogbo iyoku awon oloogun ni won see.
Eyi fihan pe koda kaa wa ni ijoba Oba, oloogun, ti omowe tabi ti awaarawa oun
to se pataki julo ni idagbasoke alailegbe.
Ki ilu
fararo ki oun amayederun wa ni ilu je Pataki julo ninu ise ti ijoba gba. Awon
ti won n tuko Naijiria ko rii bii enipe awon ni ise kankan lati se, kaka bee bi
aye awon omo won see maa daa ti gbogbo awon yooku to wanile yii yoo ma sin awon
omo won ni won n wa. Ni bii ose mesan seyin mo so fun wa nipa pe awon ti a dibo
yan ni ile igbimo asofin senate ko
ronu nipa ti ara ilu, bi ko se nipa ti ebi won.
Won ko bowo
fun egbe kankan tabi eeyan kankan, won si gbagbo pe oun ti awon ba se asegbe ni
nitori leyin odun merin awon yoo wa toro ibo pelu owo tabua. Ti eeyan ba si wo
bii iya se po to nile yii, kia ni awon eeyan yoo dibo fun won. A o rii apeere
oro yii ninu bi won se se ere itage fun wa ni ose to koja.
Bi won se
yan aare ile igbimo asofin ati awon ti yoo di ipo mu ninu iho chamber fihan pe awon asofin yii ni opo
nnkan ti won n gbe pamo.
Won ko I tii
lo osu kan nigba ti won ti bere si ni soro nipa owo aso ti won yoo maa wo.
Se ihoho ni
won wa si ile igbimo asofin ni? Abi won ko ni aso kankan rara nile yato si eyi
ti won wo wa si iho chamber yii?O ti
dun mo won lati maa gbe gbogbo isoro won sori Naijiria nitoripe a n se ijoba
awaarawa. Kilode to je pe awa ni a oo ma ra aso fun seneto? Ki lo n je wardrobe allowance? Ko sii tii tan sibe
gbogbo oun ti won nse ninu iho ti won wa yii ni won ma n gba owo re. Awon
asofin ti won soju lara awon eeyan to n jiya ju lagbaye ni o wa je pe awon gan
ni asofin tii n gbadun ju lagbaye!
Iya pupo ni
yoo je gbogbo omo ilu yii ti won ba fowo leran lati maa wo awon oloselu yii lai
pariwo kudikudie won sita. O se Pataki fun wa lati ma gba ki iwa jegudujera
awon oloselu je gaba le wa lori.
Ka tun fire
pade!
Comments
Post a Comment