Eto ilera wa gan an mehe



16
Eto ilera wa gan an mehe

A kuu rotiroti ile wa apanilerin yii. Mo si n dupe pupo lowo gbogbo awon ti won pe mi tabi ti won nko iwe ranse simi latari nnkan ti won n ka ninu abala Gbangba Dekun yii, e seun pupo! Ti a ba ni ka maa ko nipa gbogbo oun to n sele lorile-ede yii, ojoojumo ni a o maa ko olokanoojokan oro, nitoripe iseju-iseju ni awada maa n sele ninu eto isejoba wa.

Loni, awon ile iwosan waa ni a se abewo sii, tii a si ri kudie-kudie to gagaara nibe. Paapajulo, ko ti e ye ki irufe awon iwaabaje-alaibikita bayi si maa sele ni ilu ti o ro pe oun ti laju to Naijiria. 

Gbogbo eka to n boju to eto ilera ni eyan yoo ti ma ri iwa ibaje-alaibikita to ti jera debi pe o n sedin. Ilera loogun oro ni mo ma ngbo lenu awon agba onilaakaye, sugbon awon osise ilera ile yii ko rii bii ise lasan ni, pe awon si leto lati wu iwa to ba wu awon nibe. Ai-moyee-igba ni awon osise ilera ma n yan ise lodi, ti ijoba ko ba ti e gbadun, gbogbo asiko ti won ba n gba owo osu ni o ye ki won maa se ise won de oju ami. 

Kini won n pe ni pajawiri ninu eto ilera? Gbogbo eni to ba ti wa sile iwosan ni o ni kinikan ti o n se won ninu ago ara won. Paapa-julo ilewosan ti ijoba. Ile iwosan kii se ileetura kabaa sope seni awon eeyan wa sibe lati wa gbafe.
Iwa ko seni ti yoo mu mi po pupo ni awon ile iwosan ijoba. Fun apeere, mo diidi se abewo oniwadi lo si awon ile iwosan ti won n pe ni Health Centers ni ipinle eko. Aya mi si ja fun awon nkan ti oju mi ri ni gbogbo awon asiko ti mo lo ninu awon ile iwosan yii. 

Ninu okan ninu awon health centers yii, fun bii wakati meji o le ni iseju marundinlaadota (2hrs45mins) ni eeyan to to bii mejila(12) fi wa nile iwosan laisi eni ti yoo bi won pe ki lo se yin!
E yi je kayeefi fun mi ti mo si n wo ijoba ‘tuntun’ to wa nibe yii pe kini o lee se lati je ki awon osise abe re jara mose. Emi awon eeyan ko fii be jo awon osise ilera wonyi loju. 

Nigbati eeyan pataki nile yii ba lo si ileewosan ti ijoba nikan ni akolukogba ti ko nidi ma n sele, ti ara ilu lasan-lasan ba lo, igba to ba wu won ni won yoo da won loun. Won ti e ma n se bi eniipe iranlowo alailegbe ni won n se fun awon ara ilu lati maa da won loun, afi bii enipe ijoba kii san owo osu fun won ni. Ija ajaku akata ni awon ti won gbe eeyan wa ma n ja nigbamiran nigbati awon osise yii ba n se bi olorun.

Ijoba paapa nilo lati mo pe iwa aibikita kii se iwa to dara lenu ise, lara iwa ajebanu si ni, ijoba nilo lati ni ajo-amuseya to kun oju osuwon. Awa ara ilu gege bi osise paapa gbudo mo pe ki awujo wa le ni idagbasoke, ise gbogbo wa ni lati gbaruku ti emi araa wa.

Katun fire pade

Comments

Popular posts from this blog

Ijoba awaarawa yii dun bi?

Ijoba tuntun se kia…