Posts

Showing posts from June, 2015

Eto eko dorikodo

14 Eto eko dorikodo Naijiria je ilu to ma n pa eeyan lerin ni gbogbo ona. Ko fe e si ilu to ni   igboya lati huwa ibaje to orileede yii. Eyi to panilerin nipe ko si ibiti owo iwaabaje ko tii ba ni gbogbo eka nkan ti o wa ni orileede yii. Eto eko ile yi ti forisopan lati ile-iwe alakobere gan ni wahala yi wa titi ti o fi de ile-iwe agba fasiti. Iwa ajebanu to ba gbogbo eka lorileede yii naa lo ba eto eko. Bawo ni a se fe bu enu ate lu eto eko lai ya si odo ijoba ti o n tuko orileede? Iwe ofin ile Naijiria salaye pe dandan ni fun ijoba lati pese eto eko to yekooro fun gbogbo omo orileede yii, sugbon ko fi aye ijiya sile fun eka ijoba ti ko ba pese eto eko. Owo perete ni ijoba ma n ya soto fun iseto eto eko, o fee ma to ida meje ninu ogorun ti ijoba ma n ya soto ninu eto isuna fun eto eko. Ona wo ni eto eko ko nigba la ori mole? ilana eto eko paapa ko fi han pe ona ti ojo ola ile yii yoo fi ye kooro ni a n to. Ko si ilana eto eko ti o ko awon omo ile-iwe lati ...

Olopa I beegi sa

13   Olopa I beegi sa Iwa ajebanu ti di baraku nile yi. Yoo nilo gbogbo eka ijoba, ijoba fun rara re ati gbogbo mutumuwa lati se egbe leyin ara won ki a to le dekun iwa-ki-wa yii. Ti alejo ba wo orile-ede kan, awon eso asobode ati olopa ni yoo koko fi iwa orile-ede naa han won. Fun idi eyi, iwa ati ise awon olopa wa ni yoo fe so bi ase ri gan ni orile-ede yi. Ni iwoye temi, awon olopa ile yii ko see ra ni tooro, awon eso to farape oloogun yooku naa ko fi gbogbo ara yato sii awon olopa paapa. Iwa ajebanu ti je gaba le gbogbo awon ti a le pe ni eso alaabo (security) ile yi. Bi   olopa se ntoro owo lowo awon ara ilu je nkan ipenija to gontio pupo fun idagbasoke ijoba ile yi. Bi o ti le je pe iwa-ki-wa ti awon olopa nwu yi ko fi gbogbo ara jina si awon iwa ajebanu   ti oti wo wa lewu tipe, awon ti won si wa ni gbogbo eka ijoba paapa ti si gbogbo ona sile lati rii daju pe gbogbo ara ilu ni onilo lati kopa ninu iwa yeye yii. Iwa ajebanu alaibikita ti ijob...

Buhari Kaabo…sinu ainireti?

12 Buhari Kaabo…sinu ainireti? A kuu afojuba ijoba ‘tuntun’ ti Buhari yii. Opolopo afojusun si ni   awon ara ilu yii ni lori isejoba tuntun yii. Ni iwoye temi, ijoba ti o sese wole de yii kun fun ainiireti. Ogooro awon ara ilu ko tile ni oye kini awon maa ba lowo ogagun to sese de yii. Looto Ogagun ti se ijoba ri sugbon asiko igba naa yato si eyi ti a wa bayi, aye oloogun ni igba yen, ase ko le dede sele laibikita fun oun to le teyin re jade, sugbon lowo bayi, orisirisi idena ni awon oloselu ti daa le lati mu ijoba le lati se. Bawo ni ogagun se fe sise to ti seleri fun awon eniyan yii? Oni ayipada to gagaara yio sele laarin osu meji ti oun ba gbajoba, sugbon pelu iru awon ti ogagun ko sodi yii, nje yio le se awon alaale re yi? Ibeere lemi kan n beere sugbon awon nkan ti o ye ki ogagun se sun lo ja-n-tii-rere. Laarin osun meji ina iwa ajebanu to ti di baraku fun wa gbudo bere sini maa jo ajoreyin. Gbogbo awon owo ti ko nidi tii ijoba apapo ma n fi sofo danu ni o...