400 milionu
19 400 milionu Akuu aseku odun, a sii ku gbogbo igba. Lara awon ti won nfi iwe sowo simi lo ri ero alatagba ti a n pe ni internet beere lowo mi boya ijoba le te ara ilu lorun, awon kan ni awa ara ilu ko diidi ya alaimoore ni. Pe paapa julo ijoba to wa ni ita bayi ti gbe awon igbese lati mu aye derun fun awon ara ilu, awon apakan yii si fe ki awa naa fi oju ibe riran. Maa bere apileko toni lati beere pe kini ojuse ijoba? Awon ijoba wa ti fi iya je wa to bee ti a ko fi mo pe se ni o ye ki a maa gbe bi oba. Esuru ile ti yii ti padi da, seni o n le ada. Awon to ye ki o maa bo wa ti di eni ti a n bo. Ijoba ni o ni ojuse to le, to pon dandan lori ara ilu, paapa julo lati maa toju ara ilu. Nitoripe gbogbo omo ilu ni o jumo ni alumoni ti won fii nse ijoba, kii se pe eni ti won yan sipo ni lati je gaba lee lori. Olusin-ara-ilu ni o ye ki awon ti won wa ni ijoba je, kii se pe ki awon ara ilu maa sin won, tabi ki won maa bu ola kan to yato fun won. Ojuse kan pere ni ara ...