Olopa I beegi sa



13
 
Olopa I beegi sa

Iwa ajebanu ti di baraku nile yi. Yoo nilo gbogbo eka ijoba, ijoba fun rara re ati gbogbo mutumuwa lati se egbe leyin ara won ki a to le dekun iwa-ki-wa yii. Ti alejo ba wo orile-ede kan, awon eso asobode ati olopa ni yoo koko fi iwa orile-ede naa han won. Fun idi eyi, iwa ati ise awon olopa wa ni yoo fe so bi ase ri gan ni orile-ede yi.

Ni iwoye temi, awon olopa ile yii ko see ra ni tooro, awon eso to farape oloogun yooku naa ko fi gbogbo ara yato sii awon olopa paapa.

Iwa ajebanu ti je gaba le gbogbo awon ti a le pe ni eso alaabo (security) ile yi. Bi  olopa se ntoro owo lowo awon ara ilu je nkan ipenija to gontio pupo fun idagbasoke ijoba ile yi. Bi o ti le je pe iwa-ki-wa ti awon olopa nwu yi ko fi gbogbo ara jina si awon iwa ajebanu  ti oti wo wa lewu tipe, awon ti won si wa ni gbogbo eka ijoba paapa ti si gbogbo ona sile lati rii daju pe gbogbo ara ilu ni onilo lati kopa ninu iwa yeye yii.

Iwa ajebanu alaibikita ti ijoba ologun ti tari si awujo kun ara oun to se jamba fun igbesi aye awon eso alaabo. Awon  oloselu lo tun wa da gbogbo ilu ru pelu iwa kikowoje ti ko see fi we nkankan, owo to ti wole sinu eto oselu awaarawa ti a n se lowo yii kii se keremi.

Awon olopa ile yii ni oro toni yosi gbula bi igba ti ologini bay o si eku ile. Seni awon olopa waa so ago won di banki ti won ti se kokaari owo. Ona ti won fi n na eeyan bii eran. Ofe ni beeli ko kana won olopa ile yii. Iwa kiwa ti joba lookan aya waon ti won gba ise yii koja oun ti ijoba ‘tuntun’ yii le fi owo yepere mu.

Ninu ose ti a wa yii ni oro kan to mi leti pea won obinrin meji kan ja ija ajaku-akata kan, nigba ti ikan ninu won gba ago olopa lo lati lo fi ejo sun awon olopa, se ni olopa ro obirin yii lati lo salaye fun oga awon omo ganfe ti o wa ni agbegbe naa.

Kayeefi nla ni oro yii je fun mi nigbati mo rii pe ibaje ti dewa sorun awon olopa waa de bii pe igbagbo ti won ninu awon omo ganfe ti o ye ki won maa gbe si atimole ki idekun le ba ara ilu ni won fun-ra-won nse egbe to lagbara fun!

Olopa ntoro owo ni gbogbo ona, ni ojuko papako ofurufu, ile-epo, oju popo-na. gbogbo ona ti won ba ri ni won maa ngba gba owo lowo ara ilu bi enipe arebipa ni won. Botilewu kii ilu yii le to awon olopa ile yii ngba owo osu. Ki awa ara ilu gan ma fi owo yepere mu oro awon olopa ki a si ma segbe kankan fun won nigbati ajere iwaabaje ba si mo won lori.


Katun fire pade.

Comments

Popular posts from this blog

Eto ilera wa gan an mehe

Ijoba awaarawa yii dun bi?

Ijoba tuntun se kia…