Buhari Kaabo…sinu ainireti?
12
Buhari Kaabo…sinu
ainireti?
A kuu
afojuba ijoba ‘tuntun’ ti Buhari yii. Opolopo afojusun si ni awon ara ilu yii ni lori isejoba tuntun yii.
Ni iwoye temi, ijoba ti o sese wole de yii kun fun ainiireti. Ogooro awon ara
ilu ko tile ni oye kini awon maa ba lowo ogagun to sese de yii.
Looto Ogagun
ti se ijoba ri sugbon asiko igba naa yato si eyi ti a wa bayi, aye oloogun ni
igba yen, ase ko le dede sele laibikita fun oun to le teyin re jade, sugbon
lowo bayi, orisirisi idena ni awon oloselu ti daa le lati mu ijoba le lati se.
Bawo ni ogagun se fe sise to ti seleri fun awon eniyan yii? Oni ayipada to
gagaara yio sele laarin osu meji ti oun ba gbajoba, sugbon pelu iru awon ti
ogagun ko sodi yii, nje yio le se awon alaale re yi?
Ibeere lemi
kan n beere sugbon awon nkan ti o ye ki ogagun se sun lo ja-n-tii-rere.
Laarin osun
meji ina iwa ajebanu to ti di baraku fun wa gbudo bere sini maa jo ajoreyin.
Gbogbo awon owo ti ko nidi tii ijoba apapo ma n fi sofo danu ni ogagun gbudo
din ku kekere, oke aimoye owo ano-sofun-danu kun owo ijoba ti a sese le danu
yii, seni ogagun nilo lati ri si bii ijoba apapo fun ra re gan se n naa owo
lainidi. Looto ijoba awaarawa ti aare(presidential-system) ma n fowo sofun,
ninu ijoba ‘tuntun’ yii ko gbodo si aaye fun iru nkan bee.
Eto aabo
gbudo di otun. Latari ‘ogun abele’ ti o nja ilu yii lowo bayi, Ijoba apapo ni
lati tun eto aabo wa se. Soja ile wa ti di ponto, ko si agbara kankan mo fun oloogun ile yii latari bii awon Aare
tele se so won di oloselu. A ni lati ni oloogun to kaju awon isoro aini aabo
leti boda ati ileto to jasi orileede miran. Awon oloogun wa gbudo pada si
igbati ikora eni ni ijanu wa. Awon esin-o-koku Bokoharam ti gbinaya ni ile yii latara pe ijoba apapo ti so ajo
oloogun wa di yeleyele, sugbon ise nla wa
nile fun ijoba to n bo yii lati tun ajo oloogun wa se.
Ina
mona-mona to ye kooro ni yoo yi eni ati ojo ola ilu yi pada si rere. Ni
ose to koja ajo to n ri si oro ina
mona-mona ni awon se ju 1,327mwh
lo,eyi to tun mo sipe ko ibi ti ina monamona ti maa se ee lo ni ile yi. Laisi
ina gbogbo eniyan lo mo pe ko si n kan ti o see se yanju ni aye ti a way ii.
Awon egbe APC ti ni awon yio se 12000mwh ti o ba maa fi wo 2019, sugbon o koja oro afenu lasan so. Awon ara ile
yii gbudo ri ina mona-mona nii kii se ki won ma ro n pe ijoba titun yoo see.
Ireti to n
pani lerin ni opo awon eniyan ni ninu ijoba ‘tuntun’ yii. Gege bi ara ilu a ko
gbogbo fowo leran, nitori pe awon oloselu ko yato sira won pupo, paapa julo
pelu iru awon ti o wa ni ijoba ile yii. Dandan ni ki a rii pe a n pe awon ti o
nse ijoba si akiyesi to lapeere. Ao ma tesiwaju ni ose ton bo.
Katun fi
re pade.
Comments
Post a Comment