Ina mona-mona da?
10
Ina mona-mona da?
Ile adulawo
kun fun isele aba-ni-loju-je lona aimoye. Naijiria gege bi ilu to ni ‘ero’ to
poju-lo fee ni isoro ti gbogbo ile adulawo lapapo ni. Ni iwoye temi odindi saa
(century) kan yoo lo ki a to le ni igbe aye irorun, iyen ti igbesi aye irorun
ba maa de looto. ko si ohun tii kii je omo Naijiria niya: ina monamona, omi,
ona, epo, ounje, eto aabo, orisirisi oun to tii fee di afisehin ni awon ile
adulawo kekeeke miran ni o si je babara ni Naijiria.
Sugbon eyi to ko gbogbo
awon iya oniruuru yi le omo Naijiria lowo ni iwa-ajebanu alainidi. Oro ina
mona-mona ni ohun ti a o gbe-yewo ranpe loni. Ijoba apapo ta ajo NEPA fun awon
aladani ni iye owo to to ogorun meji bilionu, leyin naa ni a tun gbo pe ijoba
apapo fii owo to fee to ogorun meji bilionu
san owo agbaale(intervention fund)fun awon aladani ti o ra ajo NEPA, eyi
je isiro ago ti ko see gbe le laakaye to peye. Lakoko, awon onwoye ni gbogbo
ogun ti NEPA gan an ni ju Trilionu meji lo.
Kilode ti ijoba maa ta oun to ni
ogun to po to yen ni iye ti won taa yii? Iru ijoba wo gan ni n ta gbogbo oun to
ni fun aladani? Kilode ti awon ti won sise ijoba kii mu ise won ni okunkundun?
Ti opo fi ro pe aladani gan an ni o le see ju awon ti ijoba lo? Ijoba akotileta
ni o ye ki a pe ijoba ti nta nkan ini re fun aladani, sugbon arungun, ode, ika,
alailoye ati alaini laakaaye ni yio ta nnkan ini fun aladani tan ti yoo tun maa
fi owo ranse si aladani naa lati le se daada. Kilode ti oun o kuku lo iru owo
bee fun idagbasoke oun ti o fe ta yii?
Sugbon ibi yii ko ni oro yii fe gba loni
bikose pe kilode ti gbogbo ogbon ti won da yii ko fi yo? Idi ti ko fii sii ina
yii po ‘sugbon ko si oun to kan ara ati omo ile yii nipa iyen’ se ni koowa n wa
ona abayo aladani si oun to je isoro yii. Awon ile adulawo kereje-kereje ti wa
ona abayo si wahala ainina monamona yii, sugbon ero amunawa(generator) ni ona
abayo ti ile yii. Ko le je iyalenu,ijoba paapa nra ero amunawa(generator)!
Nigbati
ijoba ba n fi owo ero amunawa(generator) sinu eto isuna owo, oye kii awon omo
ile yii ti rii pe a ti doko dele danimo! Dandan ni fun gbogbo wa lati maa dide
lodi si inilara lori eto ijoba wa,ki a sii maa beere ibeere nipa bi igbesi aye
irorun yio se maa ba wa.
Ka tun fire
pade!
Comments
Post a Comment