Iru iyipada wo?
4
Iru iyipada wo?
Ni iwoye
temi, ad’erin posonu ni awon oloselu ile yi ni gbogbo ona. Ti a ba beere sini
maa ye gbogbo bi won se ma nse wo, se ni erin a beere sini ma pa eeke wa.
Iru-kan-naa sini gbogbo won, ko si eyi to yato, tabi to ni ife ara ilu ninu
awon egbe oselu to wa nile yii. Isejoba ile yii dun debi pe ara to ba wu
onikaluku lo maa da nibi yio wu ko le wa.
Egbe ti won pe ni ‘onitesiwaju’
laarin won kun fun ainilana kan saan ti o le fi salaye imayederun fun awon ara
ilu ju bi ara ilu se wa tele lo, sugbon won ni ipolongo ‘ayi ni lori’ sona
tiwon. Won a soro bi enipe ife ara ilu nikan lo je won logun. Oto ni ohun ti
won nso, oto ni ohun ti won nse. Iye owo to nwole si awon ipinle won ati bi won
se npin laarin awon ebi, ore, ojulumo ati awon kereje larin egbe oselu won bani
leru. Ifi aye nini-lara ko je nkan kan loju egbe yii, fun apeere Ile-iwe ijoba
apapo l’Eko ko see fi we ti ijoba ipinle ni opolopo ona, sibe owo goboi ni egbe
yii gbe lori eto eko nile yii.
Ko si idi
kankan to mo-yan-lori ti won fi-fi owo kun owo ile iwe yii, niwon igba to je pe
won ma nso pe itesiwaju egbe Pa Awolowo ni egbe awon, sugbon won se opolopo
ohun to lodi sii ohun ti Awolowo yio se to ba wa ni ipo won. Paapa julo asoju
ijoba ni ekun yi maa nsoro bii enipe oun tie dii di lase lati je le awon eniyan
lori ni, kii bikita bo se ma nsoro si awon too ndari! Ijoba yi ti ni ibasepo
ara ilu-aladani-ati-ijoba, ti otumo siwipe owo ti yio ma wo le yio ju ohun ti
ipinle yi ti ri lo nigbati ko si PPP
yii, sibe ipinle yii koo ti ri awon ohun amuludun at amaye-derun to sunmo pe
ijoba alajosepo ni won nse. Awon omo orile ede yi paapa je alawada tii kii pe
gbagbe isele, won a si tun maa ro ninu ara won pe ‘o da bi enipe ijoba yii gbon
ju ti tele lo, nitori isoro ti ijoba yii nkoju po’, igba miran won aa ni ‘ero
tipo ju ti tele lo’.
Ko si asiko kan ti kosi ero pupo fun ijoba lati bojuto.
Ona ti ijoba ba ngba lati toju ara ilu lo maa se koko. Egbe ‘onitesiwaju’ ti
won ni awon nse ko tile jo ti Awolowo lokan soso, se ninu irori ona abayo fun isoro ilu ni tabi
ninu iwa ajebanu? Bi eeyan ba sun mo won yio ripe mokaruru lasan lo poju ninu
nkan ti won dibon pe awon ti se. Fun apeere; nigbati ti koo tii si ijoba
ajumose taladani ati ara ilu PPP(Private,Public Participation) ijoba
koo pa owo to po toyi sugbon eto ohun amayederun rinle gan, Ijoba Alh. Lateef
Jakande se bebe, ile gbigbe fun awon mekunnu ni owo ti ko ga ni lara, odun die
seyin ni a gbo pe okan lara awon gomina egbe ‘onitesiwaju’ yii so pe oun ko mo
ibi ti won ti nta simenti fun talaka loto. Eto eko ti fee fori sopan kii ijoba
‘Awolowo’ 79 tode sugbon gomina igbayen sa ipa to le, to po, to sii lapeere
nipa kiko ile iwe si opolopo agbegbe ti koo ti ni ile-iwe koda awon ti o ti ni
gan tun gba kun tiwon, ile iwe yii fere kari iye omo to wa lasiko yen, sugbon
ka fi we ijoba toni?
Se ni erin yio bu jade ni eeke oluwa re bii won yio se ma
japoro didaabo-bo egbe ati ijoba won. Bi otilejepe egbe to wa loke buru jai
iyato pinisin lo waa larin awon mejeeji. Aaye pupo ko si loni lati soro, laipe
a o se agbeyewo awon iwa ati eto awon ijoba egbe wonyi. Awa ara ilu nilati mo
pe opo awon oloselu yii ko ni ife wa denu rara, ayafi ka dide lati salaye iru
idagbasoke ti a fe l’atara oun oro aje wa to ngule si akata awon oloseelu.
Ka tun fire pade!
Comments
Post a Comment