Ountaja
2
Ountaja
Ni iwoye
temi, ise kara-kata ni ise aje to po ju ni ile Naijiria loni. O je oun to pa
opo owo fun tonile-telemu julo. Ipele orisirisi si ni o wa tabi ti a le pin si.
Opolopo awon ti o ni ile ise nlala ni o fi tita ati rira se igboke-gbodo ona
aje won, koda rira ati tita gan ni awon to lowo julo nse ni ile yii. Awon
ountaja kereje ni ipenija teni da le lori.
Awon outaja kereje nile yii gbagbo
pe ipolowo oja ni agunmu oowo sugbon ero okan opolopo won nipe oti tan sibe.
Ipolowo oja gaaya nikan ko ni agunmu, bikose pe ibe gan nii ise ti bere, ka
tile duro sori ipolowo gegebi agunmu fun owo, abajade ipolowo ni kii awon
ounraja maa paara ile itaja, lati raja sugbon oun ti yio mu ounraja gegebi onibaara
duro koja ipolowo tabi ipolongo owo.
Aponle ati ayesi onibaara fee se Pataki
bii ipolowo, ka fi oyaya da oun raja loun kia si ja fafa ni bi a se nba won se.
opolopo ile ise kereje nile yi lo padanu iba-sepo to laamilaka pelu onibara, opo
ni o ma n woye pe bi ‘eyin ‘o baraa, elomiran a raa’, ni eyi ti ko ba oju mu
to. Onibaara je oba-a-fun-ni ni ounje, ati pe awon gan ni agba-ni-sise to ju
owo isowo lo. O se Pataki ki ountaja karamasiki awon oni bara gan bi enipe ti
oun ba padanu okan oun ko le rii mo, looto ti ile ise ba panu oni baara
kan a nira die ki won to le ri eni naa
pada won a si ti padanu awon melo miran
lati ari pipadanu enikan soso.
Kayeefi lo ma nje fun mi nigba ti mo ba ri bi
awon oun taja ile wa se ma nda oni baara loun, o ma njo mi loju pe awon ile ise
nla nla ma pon awon onibaara le ju awon ilese kereje kereje lo, ofeere da bi
enipe ona iba-sepo oni-baara ati ountaja lo man mu ki ile ise gbooro gan.
O se
Pataki fun gbogbo wa lati se aponle nla fun awon oni baara wa ju bo ye lo ki
aseju aponle kio wa, eyi ni ipa repete lati ko ninu bi oro aje ise wa se maa
gbooro si. Opo loye ka so ninu oro yii sugbon aa tun pade lojo miran ojoo ire.
Ka tun fire
pade!
Comments
Post a Comment