senato Kilode
11
Senato kilode?
Igbesi aye
irorun ko lee ba omo ile Naijiria. Idagbasoke kan kan ko si le wole to ile yii
wa. Ni iwoye temi ona ati je ilu gidi laarin awon ilu to ye jina si ilu Naijiria.
Gbogbo ona ni aye-daade fi n kerora lowo awon ti won n se ijoba ile yii, ti e
ba n bu enu ate lu awon kan, ee nipe riipe awon kan tie ti je ile yii kan
egungun.
Bawo ni a se
fe se ti awon Senato ile yii si? Ona wo gan ni ile yii fe gbee gba lati bo ninu
inira ti o ko ara re si? Nitoripe gbogbo awon ti won wa ni ijoba ile yii ni won
ti da ogbe to le lati we si ara ile yii. Awon senato Naijiria fi n iya nla je
ile yi ati awon ti won n gbe inu re.
Ti a ba so
pe aare n ji owo ile yii, o fee rorun lati ba aare ja nitori gbogbo eeyan ni o
ma n fee mo ti aare ba so, koda ti aare ba fe se igbonse gbogbo ilu ni o ma n
fee yoju wo bi o se n see. Sugbon awon asofin wa ma n yan kaakiri adugbo bi
enipe se ni won n se ise kan to le, ti apa wa ko le ka. Paapa ju lo, won a ma
se bi enipe a nilo la ti maa wari fun awon fun ise nla ti won n se fun wa
sugbon awon wonyii gan ni won fi agaro(Funnel) si enu owo ile yi ti won sii n
joo mu!
Omo Naijiria
to ju egberun kan o le ni ogorun mefa lo(1638) ni yoo sise fun odun kan lati ri
owo ti senato kan gba losu! Ona wo ni a se fe bo lowo irufe ikowoje yii?
Bawo ni aye
daade se fe ba ilu nigbati senato kan ba n gba owo to le ni ogun milionu losu(N29,479,749.00)? Iru ise wo gan an
ni awon senato yii n se to fi je pe omo
ile yii nilo lati sise ti yoo fi ku lati sin awon asofin ilu re?
Mo wo
saakun awon ilu ti idagbasoke gidi ti ba lagbaye, mo rii pe ko si eyi ti owo
awon asofin re to ti ile yii. Awon ilu ti o lowo julo lagbaye paapa ko san owo
to to idaji owo ti senato Naijiria n gba fun awon asofin won. Kilowa de to je
pe ilu ti ko ni ina mona-mona, ona to ja gaara , omi, eto abo, eto eko to yee
kooro, eto iwosan to dara, eto agbe to yanranti, ti ko si ni oun amaye-derun
Kankan ni o n san owo iyebiye yii fun awon asofin re?
Gbogbo omo
ile lo nilo lati ji giri si ija idagbasoke ile yii ati lati ma dake ibeere ti
yoo mu idekun ba gbogbo omo ile yii.
Ka tun
fire pade.
Comments
Post a Comment