Nibo ni irori wa wa gan?



8
Nibo ni irori wa wa gan?
Ni iwoye temi, Ijoba Jonathan tio nkase nle yi je ijoba apa,arungun,onina-ku-na,ati alailero. Ijoba ti ko bikita nipa igbesi aye irorun fun awon ara ilu ni ijoba yii. Leyin eto idibo ti egbe PDP ati oludije won si ipo are ti fidi-remi, oro owo rogunrogun ti ijoba apapo na fun eto idibo naa jade bi oun ti won gbe pooyi enu sinu afefe. Aheso  oro yii fihan pe ilese aare na owo to nlo si bii tirilionu meta lori eto idibo yii! Tii kii ba se pe ile-ise aare ati egbe yii je ika ati apa,kini idi ti won yio fina iye to sun mo iru owo yii sori eto idibo? Gbogbo ile-ise ijoba apapo ile yii loti dorikodo, eto eko nke rora, eto ilera ti dogun, eto agbe kiise oun ti ale menu ba pe ile Naijiria nse, ibaje to ba eto aabo ko see fenu so. Ijoba yi naa owo iyebiye lori ati se eto idibo ti yio gbewon pada sipo lai karamasiki awon oun to mehe ti ati menu ba yii. Tirilionu meta yii lori eto ilera nikan yio ko awon ilewosan aladani kuro nile.

Fun apeere, ti a ba pin owo yii si iye ijoba ibile to wa ni ile Naijiria (774), iye owo ti yio kan ijoba ibile kan-kan yio je: N3875968992.24, Ni eyi ti a le pe ni bilionu meta ole ogorun-mejo milionu. Ti ijoba ko ba je ika, ti awon eniyan apapo orile-ede yii na kii se ode, seni o ye ki a parapo le ijoba naa danu, ki a si ri daju pe gbogbo awon ti o kopa ninu nina owo yii fi ewon gbara! 

O ye ki awon eniyan ile yii bere sini maa kigbe ole le awon ti won sese pari eto ijoba ton lo lowo yii lori ni. Gbogbo ibi ti won ba de ki won maa gba itiju ati inira lori bii won se se owo ilu yii moku-moku. Onira fun ijoba apapo yii lati se atejade iye owo ti won ri lati ojo kini osu kefa 2009 titi di ojo kejidilogbon osu keta odun 2015, kii won si se alaye bi won se na owo naa. 

Gbogbo omo ile yii ti o ba mo bii awon ti won wa ni ijoba se se nse owo won ni suta yio ko egba jade lati lu gbogbo awon ti wa ni ijoba pa ni. Sugbon iya ti poju fun awon omo ati ara ile yii, won ri awon tio wa ni ijoba bii eni ti olorun fi sibe, won ri won bi eni ti ko see fowo kan sugbon iro ni lowolowo yii, ibo ni o gbe awon to wa nibe wole, fun idi yii gbogbo omo ile yii lo lagbara ju eni to wa nipo ijoba lo! 

Ani lati dide ni gbogbo igba lati maa beere ibeere ti yio fun wa ni esi ti o lee gba wa lowo erusin awon ijoba ti a dibo yan fun-ra wa.

Ka tun fire pade! 

Comments

Popular posts from this blog

Eto ilera wa gan an mehe

Ijoba awaarawa yii dun bi?

Ijoba tuntun se kia…