Idile Alayo
3
Idile Alayo
'Boode o dun b’igbe nilu n ri, tori ile lati n’keso rode'. Eyi je oro iran Yoruba to
se alaye ipa ti idile alayo nko ni awujo alalaafia. Idagbasoke kole jeyo laarin ilu laisi ibale
okan ninu ile. Idile je nkan gboogi ninu ki adugbo tayo laarin egbe ati ogba, o
jasi wipe ki igboro to le dara a ni lati se abojuto idile. Orisirisi idile lo
wa, awon kan kere awon kan gbooro, amo kosi eni ti ko jade lati ara
idile kan. O soro lati ya idile titi lae nitori ajobi nii je ki idile ko pa
awon eeyan po.
Baba,Iya ati
awon omo ti won bi, idile kan niyen, ti awon omo wonyi ba si nbimo lokunrin ati
lobinrin, idile yi ti ngbooro si niyen. Awon orisirisi eeyan ni yoo ma jeyo bi
won ba se ndagba sii, nitorina iwa a maa yato si ara won. Opolopo nkan lo ro
mo idile, yala idile kekere ni tabi eyi ti o gbooro. Loni die ni a o mu enu ba
nibe ati pe ipenija wa toni ni lati lo taara si gbigbe ni alafia laarin idile
wa ki awujo le toro.
Lara awon owe iran Yoruba nipe 'ti ile kan ba ntoro omo ale ibe ni koo ti dagba', sugbon ti ko ba si omo ale ninu ile naa nko? O tumo sipe ile naa ko ni daru niyen. Opo igba ni awon omo oko miran maa nhu iwa omo ale, ni idi eyi iwa rere ni eso eniyan ni idahun si igbe-si-aye alayo laarin idile. Gbogbo ebi nilo lati parapo toju ara won. Oko ati iyawo ni o nilo lati koko wa ni isokan to yanranti, eyi si ma nje ki aponle pupo wa fun won lati akata awon omo won, Nitori eyi yoo je apeere rere fun awon omo ti won ba bi. Oko ati iyawo nilati le gba eri ara won je debi ge, eyi yoo si je ki tito awon omo won rorun. Awon lokolaya ni ise pupo lati se laarin ara won.

Gbigba eri ara eni
je je oun to gaaya ninu mimu idile duro sinsin, Lokolaya ko gbudo se iye meji
nipa ara won. Ife ko lee se gege ti ko ba si ijerisi ara eni to duro san. Paapa
julo oko nilati fun aya ni ifokan-bale ati ominira lori awon ohun ti aya ba dawole. A nso ara
eni kiri ko ni ona ati mu ki nkan toro. Ominira fun obinrin ma n saba ran
idile lowo, ominira ma nfun obinrin ni igboya to to lati tesiwaju ninu gbogbo
nkan ti won ba n se. Nipa fifun obinrin ni ominira, ibale okan maa n wa ninu ile
nitori o ma nso opo obinrin di akin ni.
Ijeri ara eni si ma nse opo iranwo fun
lokolaya lati tesiwaju ninu igbe-si-aye alalaafia. Ti lokolaya ba ti wa ni
ibale okan, ona ati bojuto awon omo won maa n roru fun won. Ti lokolaya ba raye
boju to awon omo won, ti won fun won ni eko ile to yee kooro, eko iwe to
yanranti ati ti won ba si ona imo pupo sile fun won, awujo waa yoo dun yoo si
larinrin.
Ise gbogbo
idile ni lati seto to to fun idile won kii igboro le dun, eyi yoo ran alaafia
ilu lowo, yoo si se iranwo pupo fun oro aje ati eto oselu. Gegebi iran adulawo,
Idile alayo je ona abayo to se koko fun idagbasoke iran wa.
Ka tun fi re
pade!
E kú atótónu, alàgbà Èdáòtò! Olúwa yóò máa so agbára di òtun.
ReplyDeleteE seun pupo, mo dupe gidi lowo yin.
DeleteEku eto, olorun ase alekun imo yin. Idile tiyin o ni daru lagbara olorun
ReplyDeleteMo dupe pupo fun oro iyanju yin.
Delete