Liki oun gbanja?



1
Liki oun gbanja?
Ni iwoye temi, apapo orile ede Naijiria je ilu s’ogede diyan, ilu ti oun-koun tile sele lai si ibikita fun oun ti o le ti idi re yo, nitoripe ni tooto ko si oun ti yio ti idi re yo!
Ijoba apapo aa se oun to wu, beeni awon ijoba ipinle won a maa se eyi to wu   awon naa. Itapa si ofin,itapa si ‘ipinu idagbasoke’ fun alara ijoba gan ko sowon, ni opolopo igba aisedeede ninu ‘aba idagbasoke’ tabi itapa si ofin taara ma n sele lati owo awon oludari isejoba apapo orile ede yii ati awon ijoba ipinle. Fun apeere, ijoba ipinle Eko lo se ofin ki okada ma rin ni oju opopona asare jageere*, sugbon asiko atidibo sun mole tan eyi dii oun ti an fi owo yepere mu, Ijoba yii kan na ni o so owo ile eko giga di ti alaja gegere sugbon nigba ti eto idibo sun mole tan odi oun ti o see ge wale. Gbogbo awon eleyi ko ni a fe soro le lori loni,oseese ki aye wa fun wa lati ko nipa awon wonyi ni ojo miran ojoo re.

Atoto-nu teni da lori lile poster ni ipinle Eko, Ijoba ipinle Eko nna owo ribiribi lori ipolongo ki awon olugbe ipinle eko ‘ma se te oju ipinle Eko mole’. Bi won se nse ipolongo lori redio ni won se ti amohun-maworan, bee ni won se ‘apeere’ bo se ye ki a se awon ipolongo wa. Ijoba tile pese awon ona abayo orisirisi fun piponlogo irufe eyi-ke-yi tii ‘eyan’ ba fe, opolopo patako gbangba bii ti oke okun ati awon patako ti nlo ina naa lo tun wa fun ipolongo. Leyin igba ti ijoba ti wa se gbogbo eleyi, O wa rii daju pe gbogbo poster ti won ba ti le ni ajo LASAA ma nya kiri gbogbo igboro won a si fo ibe ko mo toni-toni, ajo yii tun ma nse kilokilo fun awon ti won ba nle poster si ara ogiri kaa kiri. Eleyi se akoba pupo fun gbogbo awon onise kereje kereje ti ko ni owo lati se ipolongo bii awon eyi ti ijoba se ala re sile. 

Awon ti won maa nse isoji, Wolima, GCE*, Ose keekeke, Obituary*, Ere ori-itage, Ile Iwe ati opolopo ise kereje ko lee polongo bii ti igba kan mo. 
Ijoba ni awon poster wonyi nda panti sile ati pe ko buyi kun ipinle wa nitori ifoju-sun fun megasiti ti a nreti. Lenu kope pupo yii ni eto idibo wole de, o kuu feere ki a dibo, nise ni poster lile kii se ese mo nipinle Eko! Gbogbo egbe oselu nii nle poster,APC,PDP,LP,NCP,APGA ati beebe lo. Sebi won ni bo se wa ni liki bee naa lo wa ni gbanja? Kilode ti awon tii ki se oloselu tabi awon ti ko polongo oselu ko le le poster lasiko to ba wu won? Kilode to je pe awon oloselu nikan lo lase lati le poster ti LASAA ko lee ya? Bawo ni obo se se ori ti inaki ‘o se? Eyi fihan pe  awon oloselu wa je anikanjopan, alailooto, amo-ta-ra-eni-nikan ati ika, tii kii se pe won nife mekunu lokan bi ko se ti arawon nikan. Sugbon oro yii wa lowo awa ara ilu lati topinpin bi ojo ola wa yio se tesiwaju nipa mi mo eto wa.

Ka tun f’ire pade!

Comments

Popular posts from this blog

Eto ilera wa gan an mehe

Ijoba awaarawa yii dun bi?

Ijoba tuntun se kia…