Eto eko dorikodo



14

Eto eko dorikodo

Naijiria je ilu to ma n pa eeyan lerin ni gbogbo ona. Ko fe e si ilu to ni  igboya lati huwa ibaje to orileede yii. Eyi to panilerin nipe ko si ibiti owo iwaabaje ko tii ba ni gbogbo eka nkan ti o wa ni orileede yii. Eto eko ile yi ti forisopan lati ile-iwe alakobere gan ni wahala yi wa titi ti o fi de ile-iwe agba fasiti.

Iwa ajebanu to ba gbogbo eka lorileede yii naa lo ba eto eko. Bawo ni a se fe bu enu ate lu eto eko lai ya si odo ijoba ti o n tuko orileede? Iwe ofin ile Naijiria salaye pe dandan ni fun ijoba lati pese eto eko to yekooro fun gbogbo omo orileede yii, sugbon ko fi aye ijiya sile fun eka ijoba ti ko ba pese eto eko.

Owo perete ni ijoba ma n ya soto fun iseto eto eko, o fee ma to ida meje ninu ogorun ti ijoba ma n ya soto ninu eto isuna fun eto eko. Ona wo ni eto eko ko nigba la ori mole? ilana eto eko paapa ko fi han pe ona ti ojo ola ile yii yoo fi ye kooro ni a n to.

Ko si ilana eto eko ti o ko awon omo ile-iwe lati inu asa ati ise won nile yii, bikose eyi to n fi ilu London han wa ju bi a se mo osogbo lo. Ilana eto eko to bu ola fun oba’binrin Queen Elizabeth ju ti gbogbo oba ile yii lo. Eto eko ti ko mo pe awon baba wa ti mo odo ‘rifa naija’ saaju Mungo Park, eto eko ti ko je ki awon akeko mo pe ki ede geesi to de awon eya orisirisi ti n ba ara won soro ti won si ti ba ara won lo fun bii egebrun odun ki oyinbo to de.

Eko ti o n gbin sinu awon awon akeko pe eru ni wa ti iwa ati ise awon ti o n tuko eto eko naa si fee jo ti eru ti o gbiyanju lati ji nkan ti yoo fi ranse si awon eeyan re ni ile okeere. Eto eko ti ko ri gbogbo yara ikeko bii alapa ti o nilo atunse gidigan. Eto eko ti ko ri awon oluko ti n s’egusi ninu ogba ile iwe ti o si tun ma n sa lenu ise.

Kikidaa enu lasan ni ijoba fi n da si eto eko nile yii, bi o tile jepe isoro to n koju eto eko ti gagaara latarape ijoba ti gbagbe eto eko si egbe kan sugbon o si ni atunse ti o le waye kikakia ti ona abayo si awon isoro eto yoo fi ma yoju . Lati fi omo si ile-iwe-oniwe-mewa nile yii ti di ogun abele. Gbogbo awon alaale ijoba Naijiria ni awon eeyan ti fi owo gba si egbe kan.

 Awon osise ijoba ti ri agbegbe yen bii ona kan soso lati tan gbogbo isoro aye won. Sugbon ijoba to ba setan lati mu eto eko ni okukundun yoo ji giri tako iwa ajebanu ti o yii eka yi lara bii igbati aso aala opa kan ba ja sinu epo pupa. Dandan ni fun gbogbo omo ile yii lati rii pe aye daade ba wa nipa sise akiyesi awon kudiekudie agbegbe wa ki a si maa benu ate lu lohun rara.
Katunfire pade.

Comments

Popular posts from this blog

Eto ilera wa gan an mehe

Ijoba awaarawa yii dun bi?

Ijoba tuntun se kia…