24 Se ina monamona naa ti de ile yin?



24

Se ina monamona naa ti de ile yin?

Lara awon ti won nko iwe ranse si mi beere ibeere lowo mi pe boya mi o ri nnkan-kan ti o daa ninu ijoba ti a n se lowo yii. Onkowe naa ni bi mi o ti e ri nnkankan  o ye ki n ri ina oba to ti wa kaakiri.

Looto ni, o jo pe ina oba ti duro ‘deede’ de ibi kan ni awon agbegbe kan, sugbon opolopo awon agbegbe ni koo tii ni opo ina debi pe won yoo ni ina. iwoye ti mo ni nipa ilu wa nigba-miran nipe, ki oloye Obafemi Awolowo yoju lati oke ki o si ri ibi ti awon eya to ni erongba nla fun ba ise de. 

Bawo ni baba Awolowo se maa wo awon ‘omo’ ti o fi sile, bawo ni awon omo naa se ndari ilu ti Awolowo ja fun ki o to lo?
ni 1959 ni Awolowo ti mu telifisan wa si ile yoruba, 2015 opolopo yoruba koo ti ri ina wo telifisan naa. Awon ona ti baba ti da konta sii lati aye ojo yen si ni opolopo awon ona ti o wa ni igberiko wa do ni. Bawo ni Awolowo yoo se maa wo igbe aye awon omo yoruba ni morere ti o wa bayi ti o tin je pelu awon awo ire?

Bawo ni Tafawa Balewa se maa ma wo gbogbo ile Hausa? kini o fe so nipa ikowoje ti ko mo eya mo ni orile-ede yii? bawo ni yoo se maa wo idagbasoke ton ba apo awon oludari apa ariwa Naijiria nigbati ijoba ti bo si owo eya won? Ti gbogbo awon oloselu won nlowo ti won si so eto eko di eewo fun awon mekunu ile Naijiria ti awon Balewa ja fun?

Bawo Ahmadu Bello yoo se ma wo oun ti eya re di pelu ijiya nla ti won fi n je awon alaise to n gbe ni apa adugbo won? Bawo ni yoo se ri Boko Haram? Bawo ni yoo se maa wo awon oloogun to ti di yepere ti apa won ko le ka ipenija laarin ilu won. Bawo ni yoo se maa wo ile-ise papako ofurufu to je pe ki o to di 1950 ni won ti n lo oko ofurufu ni Kano.

Bawo ni Nnamdi Azikwe yoo se ma woo oun ti eya re di?  Nnamdi Azikwe to di awokose fun awon eeyan bi Kwame Nkruma ati Obafemi Awolowo nigbakan ri, ti eto eko ko wa je nnkankan mo ni ile re?
Bawo ni azikwe yoo se ma wo awon omo yanmiri ti won ko lee gba ona kan taara ni ilu. Bawo ni yoo se ri eto eko ile ibo si? bawo ni yoo se wo oro aje orileede to fi sile ni bii ogbon odun seyin?

Kini awon omo orileede yi yoo se jabo fun awon baba won yii nipa bi a se ndari ara wa pelu aidagbasoke ti a ko ara wa si. Mi o so pe awon ti mo daruko yii pe, sugbon ife eya ati orileede won je won logun gidi debii pe won mu idagbasoke alailegbe ba iran won ni asiko igba tiwon.

NEPA ti mu ina de si adugbo yin, sugbon egbeegberun adugbo ni ko ni ina ri, opolopo ni koo ti mo pe ona to ni oda si wa ni naijiria.
Ojuse wa gege bi ara ilu ni lati maa wa igbe aye to daade fun ara wa laini ro bi awon oloseluse se ba wa tan.

Ka tun fi re pade!

Comments

Popular posts from this blog

Eto ilera wa gan an mehe

Ijoba awaarawa yii dun bi?

Ijoba tuntun se kia…