25 Mista Gomina leekan si
25
Mista Gomina leekan si
Adupe pupo
lowo gbogbo awon ti won npe wa ni ti gidi lati fi erongba won han lori awon
ohun ti a n ko ninu iwe Iroyin-Owuro, paapa julo ninu abala Gbangba Dekun. Eyi fihan pe ko see se
lati je adagun nigbati eeyan ba nko nnkan sinu iwe-iroyin. Ope pataki lowo yin
oo!
Gege bii ise
mi lati maa yannana isejoba ati iwa i-bara-eni-gbe pelu eto oselu, ni eyi to
jinle ninu eto oselu awaarawa ti a n se lowo yi, mi o ni se alaise bee ni ose
yii. Ni ose meji seyin, mo pe akiyesi wa
si awon aisedeede awon oko-ajagbe-ejo, gbogbo oju si ni o ri abajade gbogbo
ariwo ti mo n pa ni ose to tele.
Ilu Eko tii
n jo oun to dorikodo bayi. Awon awako tie ti gbe iwakiwa wo, isowo wa moto ni
ilu Eko ti yato bayi, eni to ku ni a ni ko kuu re, sugbon Gomina tuntun tun ti
ru oku koja ile! Ewo ni gbogbo ki ilu di alailofin bii eyi ti a n gbe lowo
bayi? Ilaji ina ti n pe oko ranse (traffic
light) ni ko sise mo. Ina kan tie ma n tan lori birij Carta, ti eeyan ba nkoja lori afara eleeketa(3rdMB) yoo ri ina naa
ti to bi aro(blue) sugbon lati igbati baba Epe ti gba ijoba ni gbogbo iru nnkan
bayi ko ti sise mo. Awon nnkan ti a mu enu ba yi je awon nnkan to kere gan-an
sugbon ti o ma nje ki awon eeyan mo bo ya alabojuto ni o n dari won.
Ojoojumo ni
ona wa n baje si ni ipinle Eko, gbogbo re dake roro bi enipe ko si olori ni
aganyin. Ipinle Eko tii fe ri iru gomina bayi ri lenu ijo meta yii. Idi ti o fi
n se mi ni kayeefi nipe egbe kan naa ni awon mejeeji ti won gba ijoba lowo ara
won, se o wa tunmo si pe gomina to lo ba gbogbo nnkan je ni? Abi ki lo wa de to
je pe awon oko agbero-gberu gan-an n gba ona BRT ti ko si si eni ti yoo ye won lowo wo, gbigba one way gan-an o gbeyin mo bayi ni
ipinle Eko.
Gbogbo awon
iwa palapala ti awon eeyan gunle ni ipinle Eko lowo bayi ko ni nnkan ire kan ti
yoo se fun ijoba to de yii. Tandi ni a ni ko moo jo, tandi-tandi to gbode yii
ko n pa wa lerin ainidi ni. Ipinle to ni ero to poju ni ipinle Eko, ipinle yii
wa lara ipinle to lowo julo ni orile-ede yii ni, ko ye ki kudie-kudie wa po
bayi. Awon kan ti se ijoba ipinle yii ri ti won si ko opolopo oriire ba ipinle
yii, to je pe titi di oni a koo i tii ri iru awon ijoba bee. Okan pataki ni Oloye
Lateef Jakande, iru awon baba bayi ni won jo eni ti o ni ife ara ilu lokan.
Sugbon dandan ni fun wa lati maa se akiyesi awon oloselu waa ati bii won se n
sejoba le wa lori, ki a si maa pe won si akiyesi, kii se ka maa se agbodegba
fun won.
Katun fire
pade!
Comments
Post a Comment