E je ka ji giri




20

E je ka ji giri

Akuu ojo meta kan. Ojoojumo ni awon oloselu Naijiria n fi iru eya ti won je han. Awa omo Naijiria paapa naa ko gbeyin nipa riran awon oloselu waa lowo ninu iwa ibi won.
 Nigbati awon kan ba n bu enu ate lu awon oloselu nipa iwa aibikita ti won maa n wu, se ni opolopo omo ile yii ma n segbe leyin won bi enipe owo ti awon oloselu yii n ji yii won jo ma n na ni. Naijiria nikan ni mo ti ri ilu nla to tobi daada ti o si ni ero to po gan ti ko si ni nnkan amayederun kankan, ilu bii Ibafo ni ipinle Ogun je ilu to tobi gbayau lasan, ti ko si ni ireti igbadun kokan to jo ti ijoba.

Ibafo ni opolopo awon ti won ngbe ni ilu eko tele ri lo ko ile si ti won si n gbe, paapa julo nitori opolopo fe di onile lori, ilu to ni ero to po to fee to orileede mii yii ni ko figbakan ri gbadun oun amaye-derun kankan lati odo ijoba, yala ijoba ibile ni, ipinle tabi ijoba apapo. Ko si ina oba, ko si omi, ko si ona kankan to jo ti eeyan to ni laakaye, sibe awon ara ilu yii ndibo fun egbe oselu kan ni asiko idibo.

Iwa awa omo Naijiria npa mi lerin! Ilu Epe to bi gan-an ni,  okan lara awon ilu to tipe gan-an ni ti o si ni itan nla ni ipinle Eko ni ilu Epe. Gege bi ilu to gbooro ti o si ni ogooro awon eeyan ti won ngbe ni ibe, o ye ki idagbasoke to le daada ti ba ilu yii. Awon ara ilu yii naa n dibo, yoo si ya ni lenu pe ijoba ipinle yii ma n pariwo bi awon se ti so gbogbo eko di orun fun gbogbo awon olugbe eko, sibe idagbasoke ti igbalode kankan ko see fi oju ri ni ilu yii.

Akaimoye iru awon ilu bee to yapa ni orileede yii ti idagbasoke eepini ko foju han nibe, sibe awon ara ilu yii ndibo fun awon oloselu! Iya ajepajude ti mo wa lara ni ilu yi. Ko si eni ti o fe ji giri mo lati ranti awon eeyan leti irufe aye to ye ki won maa gbe. Enikan fii iwe ranse simi lori email, o ni se mo ro pe igbe aye irorun le ba Naijiria bi? O ni se lo ye ka kuku fi awon oloselu sile ki won maa se ti won ki awa naa si maa se ti wa.

Sugbon mo gba pe igbe aye irorun le ba wa ni orileede yii, iyen ti awa gan naa ba fe ki ilosiwaju ba wa. Ona ti awon oloselu fi n gbe owo ilu yii si apo ara won jo pe opolo awon ti won n dari ilu yii ti daru. Ogba ti won ti n toju were si ni o ye ki opo ninu awon ti won dari ilu yii wa. Fun apeere, asiri kan sese tu pe minista Naijiria kan n ta agba milionu epo robi lojo kan lai ko owo re fun ijoba.

Ti eeyan kii ba se were, asiko igba yen ni won ta agba epo kan ni ogorun dollar($100), owo ti won yoo ri je ogorun milionu dollar ni ojo kan, to tumo si N21500000000 ni ojo kan. Nje iye owo yii ko ni so awon ilu ti mo ti menu bayii di ilu oke okun? Sibe oun ni awon kan nko si apo ti won si nyo! Awa ara ilu gan ni ko si nkankan ninu ori wa, ti a ma n fi ojoojumo segbe leyin awon oloselu.

Igbe aye rere lo ye ki a ma ja fun ni gbogbo igba, kii se ki a ma paro mo Olorun lori oro aje waa. Owo wa ni a le fi tun oro aje waa se. Ki a pada ninu iwa aponle ti ko ye fun awon oloselu nitori awon gan ni won n ba aye orileede yii je. Ojuse wa ni lati maa wa iderun ati idekun fun ara wa.

Ka tun fire pade!

Comments

Popular posts from this blog

Eto ilera wa gan an mehe

Ijoba awaarawa yii dun bi?

Ijoba tuntun se kia…