Ipinle Eko
21
Ipinle Eko
Ope mi ko
lopin lodo ogooro awon eeyan ti won nka iwe Iroyin Owuro paapaa julo awon ti
won nka abala Gbangba Dekun, ti won
sii n fi orisirisi iwe ranse lori ero komputa ati awon ti won n pe mi. Eyi fi
han pe apileko yii ko jasi asan, awon onkawe yii ti won si n fi ero tiwon naa
ranse je okan ninu ona ti agbara wa fi n ga sii, ti a sii fi n mo pe yato si pe
awon eeyan nra iwe Iroyin Owuro yii, won n kaa, o si n ye won, E seun pupo.
Gege bii oro
kan ti mo ma ntenu mo, pe ko si igba ti oro ko kun le repete fun wa lati dasi,
aaye le ma gba wa lati dasi gbogbo re leekan naa ni. Loni eto aabo ipinle Eko
ni aa o menu ba die ninu bo se ri ni akoko ti awa yii.
Ipinle Eko
je ipinle lo fee ni eeyan to po ju lo ni ilu kan soso ni ile Afrika, nitori o
fee da bi enipe gbogbo ileto lo ti ja po mora won ni ilu yii. Laarin ijoba
apapo ati ijoba ipinle, Eko ti fee ni to ogun milionu eeyan ti o n gbe inu re.
Eyi si fi han pe ko si orileede kan to ni ero to po to yi ni ilu kan soso ni
Afrika. Nitoripe awon ilu gbogbo to wa ni ipinle Eko ti japo ni ijoba ana ti
amofin Babatunde Fashola je gomina re se ni awon yoo se agbateru eto ilu to gbooro
fun Eko, ti won n pe ni Megasiti.
Eko si ni
ilu to n pawo julo ni gbogbo ipinle to wa ni orileede yii. Fun idi eyi, ipinle
yii naa ni o ni iye eeyan ti yoo boju to ju lo ni orileede yii. Pelu iru
isejoba ti Eko ti fi oju ri lati nkan bii odun meedogun seyin, ko ye ki awon
nnkan kan tun maa mehe ju bo se ye lo.
Fun apeere,
eto aabo! Owo goboi ni ijoba ipinle Eko n ya soto fun eto aabo, yato si iyen,
ijoba tun se eto kan ti awon omo ilu naa le fi da si eto aabo ti won pe ni Security Trust Fund . Sibe se ni eto
aabo ilu yii n baje si.
Gbogbo
opopona wa ti di eru jeje fun elese ati onimoto bayi. Ji-ji-nigbe ko lounka mo,
awon igaara olosa ti wa wole wa si ipinle yii gan ju bo se ye lo. O fee le ma
si ojo kan ki awon olosa ma digun jale ni agbegbe kan mo bayi.
Awon omo
keekeeke kan tie wa ya wo ipinle Eko lati oke oya bayi ti won ntooro owo,
latari oun ti oju awon eeyan ri ni oke oya lojo itunu aawe to lo, to je pe awon
omo kekere ni won yin ado oloro, eyi ti wa je ki aya awon eeyan wa loke bayi pe
to ba pe to ba ya awon wonyi naa le di afe-mi-sofo.
Ni asiko eto
idibo to koja, gbogbo awon oludije ni won seleri eto aabo to nipon fun awon ara
ilu. Ti o ba si je pe egbe miran lo wole ni, seni awon eeyan o ba ni boya won
ko ii tii fi ona ijoba han eni to sese de. Sugbon egbe ti ati nlo lati odun
meedogun yii naa lo si n dari wa, ki lo wa de ti ko ii tii si ona abayo to
munadoko lori oro eto aabo ni ipinle ti o je pe gbogbo nkan ibe owo ni?
Gbogbo ileri
ti ijoba ba se lo ye ki o mu se! ko si eni to nwa onidan, sugbon o fee je pe
eni ti o ba kun oju osunwon julo ni oye ko je oye ni, ti o ba wa ri bee oye ki
awon ti won tuko ijoba wa maa ri isegun lori awon ohun to ba n ba wa finra. Awa
ara ilu naa si ni ise pupo lati se, o ye ki a maa beere ibeere lori eto wa lowo
oloselu, kii se ki a ma je agbodegba fun won.
Ka tun fire
pade!
Comments
Post a Comment