Mista Gomina
22
Mista Gomina
Ni iwoye
temi, ipinle Eko ni o fee je ilu to duro deede julo ni Naijiria. Lati odun
merindinlogun o le ni eeya egbe kan naa ti n dari eto ijoba ipinle yii. Ojo idibo
lee le gan-an, o si le fee di ogun, sugbon egbe kan naa yii ni o n jawe
olubori.
Gbogbo
atotonu yii wa ja sipe ko ye ki ilosiwaju ma maa tesiwaju, paapa julo ninu eto
ise joba ipinle Eko. Ijoba to wa ni ipinle Eko ma n se aya-gban-gba pe awon je
egbe ti n da si oro mekunu, ti a mo si ‘welfarist
party’ . Ko da won ma n so pe egbe ti o n wa ilosiwaju fun omo-niyan ni
egbe won. Sugbon gomina ti o soju egbe naa koja lo owo agbara to po gan paapa
ti o fe jo ti oloogun.
Ise
itesiwaju ko fi gbogbo ara le to bi a se muu ninu ijoba to sese koja l’Eko yii,
bee si ni ko ye ko tun fi gbogbo ara wo le to bi oga agba tuntun see n mu lo
yii.
Ki a ma baa
si ara wa gbo, gbogbo ilu ni yoo ni ofin to dee. Ti won ba n sese n tun ilu se
tabi ti won ba ngbiyanju lati so ilu di tuntun, orisirisi ifarada ni awon
olugbe maa n nilo lati fi yanju awon ohun ti o ba kan won ninu aba ijoba.
Sugbon kii se pe ki ijoba maa se isejoba laisi irokan si awon olugbe ilu inu
re.
Apeere kan
nipe awon oja kan ti wa ti awon eeyan ti n taja tele. Ti ijoba ba fe tun oja
naa to tabi ti won ba fe tun ko, ijoba nilo lati pese paaro fun awon ti won n
taja nibe, ki igbe aaye irorun le ba won.
Ti ijoba ba
fe ko ile tuntun to rewa, to dun-un gbe si agbegbe kan ti awon eeyan tin gbe
tele, dandan ni fun ijoba lati pese ibomiran fun awon olugbe ile tii tele ki
won si san owo gba ma binu fun won. Kii se pe ki ijoba so pe to ri awon fe ki
ilu dan, ko dun, ki won si maa ko inira to gagaara ba awon olugbe ilu ti won
dari.
Gomina to lo
l’Eko se opolopo awon nkan to ko inira alainidi ba awon ara ilu. Nigbati eto
idibo waye, o je ko nira pupo fun egbe ree lati jawe olubori, looto egbe re
pada segun, sugbon isegun yii ko da bi ti igba ti oun fe gba ise lowo oga re ni
igba akoko.
Gomina to
sese de ko jo eni ti o mo oun to n se. Itesiwaju ni o ye ki isejoba naa je, o
si ye ko dan moran, o ye ko rorun lati yo kudie-kudie ijoba ti tele kuro. O tun
wa ye ko rorun lati mu awon ohun to dara ninu ijoba to lo lati fi se akaso fun
idagbasoke ipinle Eko lapapo.
Asiko ti n
lo pupo. Awon eeyan ko si tii ri nkankan ti o jo pe gomina naa nsise. ti o ba
je ijoba apapo ni, won aa ni egbe tele ri ti ba orileede je. Se o wa je pe
gomina to lo ba Eko je ni? A bi ki lo de ti gomina tuntun tun fi n faa bi igbin
lati se awon oun to ye. Opolopo awon nkan tun ti n baje sii.
Ko ye ki
awon ara ilu sun lo nitori won dibo fun enikan to jo eni ti won n wa bii
mesaya, se ni o ye ki gbogbo wa di oju ni alakan fi n sori lori oro ilu wa.
Ka tun fi re
pade!
Comments
Post a Comment